Ìfihàn 18:2-8 BMY

2 Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:“Bábílónì ńlá ṣubú! Ó ṣubú!Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù,àti ihò ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo,àti ilé ẹyẹ àìmọ́ gbogbo,àti ti ẹyẹ ìríra.

3 Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ nigbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú.Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè,àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”

4 Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé:“Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,kí ẹ ma bàá ṣe alábàápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,kí ẹ ma bàá si ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.

5 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,Ọlọ́run sì ti rántí àìsedédé rẹ̀.

6 San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.

7 Níwọ̀n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó,tí ó sì hùwà wọ̀bìà,níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́;nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé,‘Mo jókòó bí ọbabìnrin,èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’

8 Nítorí náà, ní ìjọ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé,ìkú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn;a ó sì fi iná sun ún pátapáta:nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.