10 Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jésù mú: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jésù ni ìsọtẹ́lẹ̀.”
11 Mo sì rí ọ̀run sí sílẹ̀, sì wò ó, ẹsin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòótọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun.
12 Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkárarẹ̀.
13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọrùn tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn lórí ẹ̀sin funfun.
15 Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi ṣá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn:” ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè.
16 Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:ỌBA ÀWỌN ỌBA ÀTI Olúwa ÀWỌN Olúwa