1 Ańgẹ́lì karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀ mo sì rí ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá: a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un.
2 Ó sì sí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èèfín ìléru ńlá, òòrùn àti ojú sánmà sì ṣóòkùn nítorí èéfín ihò náà.
3 Àwọn eṣú sì jáde ti inú èéfín náà wá sórí ilẹ̀: a sì fi agbára fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbára àkéekèe ilẹ̀.
4 A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn.
5 A sì pàṣẹ fún wọn pé, kí wọn má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n kí a dá wọn ni oró ni oṣù marùn-ún: oró wọn sì dàbí oró àkéekèe, nígbà tí o bá ta ènìyàn.
6 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn yóò sì máa wá ikú, wọn kì yóò sì rí i; wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ikú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
7 Ìrísí àwọn eṣú náà sì dàbí àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí o dàbí àwọn adé wúrà wà, ojú wọn sì dàbí ojú ènìyàn;