12 Nítorí náà lẹ́yìn tí ó wẹ ẹṣẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti mú agbádá rẹ̀, tí ó tún jókòó, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ ohun tí mo ṣe sí yín bí?
13 Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa’: ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.
14 Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti Olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹṣẹ̀ ara yín.
15 Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín.
16 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ-ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ.
17 Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń se wọ́n!
18 “Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ: èmi mọ àwọn tí mo yàn: ṣùgbọ́n kí ìwé-mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’