15 Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín.
16 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ-ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ.
17 Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń se wọ́n!
18 “Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ: èmi mọ àwọn tí mo yàn: ṣùgbọ́n kí ìwé-mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’
19 “Láti ìsinsìn yìí lọ ni mo wí fún un yín kí ó tó dé, pé nígbà tí ó bá dé, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé èmi ni.
20 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán, ó gbà mí; Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi.”
21 Nígbà tí Jésù ti wí nǹkan wọ̀nyí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú nínú rẹ̀, ó sì jẹ́rìí, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.”