5 “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èṣo ọ̀pọ̀lọpọ̀: nítorí ní yíyara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan.
6 Bí ẹnìkan kò bá gbé inú mi, a gbé e sọnù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka, a sì gbẹ; wọn a sì kó wọn jọ, wọn a sì sọ wọ́n sínú iná, wọn a sì jóná.
7 Bí ẹ̀yin bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá sì gbé inú yín, ẹ ó bèèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, a ó sì ṣe é fún yín.
8 Nínú èyí ní a yìn Baba mi lógo pé, kí ẹ̀yin kí ó máa so èṣo púpọ̀; ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.
9 “Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì fẹ́ yín: ẹ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.
10 Bí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, ẹ ó dúró nínú ìfẹ́ mi; gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.
11 Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ayọ̀ mi kí ó lè wà nínú yín, àti kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.