14 Òun ó máa yìn mí lógo: nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín.
15 Ohun gbogbo tí Baba ní tèmi ni: nítorí èyí ni mo ṣe wí pé, òun ó gba nínú tèmi, yóò sì sọ ọ́ fún yín.
16 “Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”
17 Nítorí náà òmíràn nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kí ni èyí tí o wí fún wa yìí, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi: àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba?”
18 Nítorí náà wọ́n wí pé, kí ni èyí tí ó wí yí, nígbà díẹ̀? Àwa kò mọ̀ ohun tí ó wí.
19 Jésù sáà ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi?
20 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ẹ̀yin ó máa sọkún ẹ ó sì máa pohùnréré ẹkún, ṣùgbọ́n àwọn aráyé yóò máa yọ̀: inú yín yóò sì di ayọ̀.