7 Nísinsìn yìí, wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun gbogbo tí ìwọ ti fi fún mi, láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni.
8 Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.
9 Èmi ń gbàdúrà fún wọn: èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n íṣe.
10 Tìrẹ sáà ni gbogbo ohun tí í ṣe tèmi, àti tèmi sì ni gbogbo ohun tí í ṣe tìrẹ, a sì ti ṣe mí lógo nínú wọn.
11 Èmi kò sì sí ní ayé mọ́, àwọn wọ̀nyí sì ń bẹ ní ayé, èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, pa àwọn tí o ti fifún mi mọ́, ní orúkọ rẹ, kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní gẹ́gẹ́ bí àwa.
12 Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fifún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ.
13 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn.