13 Nítorí náà nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jésù jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Hébérù, Gábátà.
14 Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ-ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà:Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!”
15 Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, “Mú un kúrò, mú un kúrò. Kàn án mọ́ àgbélébùú.”Pílátù wí fún wọn pé, “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí?”Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, “Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kábíyèsí.”
16 Nítorí náà ni ó fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
17 Nítorí náà, wọ́n mú Jésù, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnra rẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Hébérù tí à ń pè ní Gọlígọtà:
18 Níbití wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jésù sì wà láàárin.
19 Pílátù sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi í lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni, JÉSÙ TI NÁSÁRẸ́TÌ ỌBA ÀWỌN JÚÙ.