38 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Jóṣéfù ará Arimatíyà, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pílátù kí òun lè gbé òkú Jésù kúrò: Pílátù sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jésù lọ.
39 Níkodémù pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru lákọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjíá àti álóè wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́rún lítà.
40 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn.
41 Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì titun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tíì tẹ́ ẹnìkan sí rí.
42 Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jésù sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; nítorí ibojì náà wà nítòòsí.