21 Nítorí náà, Jésù sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.”
22 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí mímọ́!
23 Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dá dúró, a dá wọn dúró.”
24 Ṣùgbọ́n Tómásì, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Dídímù, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jésù dé.
25 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!”Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́!”
26 Lẹ́yìn ijọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tọ́másì pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlèkùn, Jésù dé, ó sì dúró láàrin, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.”
27 Nígbà náà ni ó wí fún Tọ́másì pé, “Mú ìka rẹ wá níhín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”