21 Nígbà tí Pétérù rí i, ó wí fún Jésù pé, “Olúwa, Eléyìí ha ńkọ́?”
22 Jésù wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kínni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
23 Ọ̀rọ̀ yìí sì tàn ká láàrin àwọn arákùnrin pé, ọmọ-ẹ̀yìn náà kì yóò kú: ṣùgbọ́n Jésù kò wí fún un pé, Òun kì yóò kú; ṣùgbọ́n, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kínni èyí jẹ́ sí ọ?”
24 Èyí ni ọmọ-ẹ̀yìn náà, tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí àwa sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.
25 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun mìíràn pẹ̀lú ni Jésù ṣe, èyí tí bí a bá kọ̀wé wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé gbogbo ayé pàápàá kò lè gba ìwé náà tí a bá kọ ọ́. Àmín