34 Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí títí láé.”
35 Jésù wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òrùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé.
36 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin ti rí mi, ẹ kò sì gbàgbọ́.
37 Gbogbo èyí tí Baba fi fún mi, yóò tọ̀ mí wá; ẹni tí ó bá sì tọ̀ mí wá, èmi kì yóò tà á nù, bí ó tí wù kó rí.
38 Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti má a ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.
39 Èyí sì ni ìfẹ́ Baba tí ó rán mi pé ohun gbogbo tí o fi fún mi, kí èmi má ṣe sọ ọ̀kan nù nínú wọn, ṣùgbọ́n kí èmi lè jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.
40 Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo ọmọ, tí ó bá sì gbà á gbọ́, kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.”