1 “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, fi igi kan àpótí kan kí o sì gun orí òkè tọ̀ mí wá.
2 N óo kọ ohun tí mo kọ sí ara àwọn tabili ti àkọ́kọ́ tí o fọ́ sí ara wọn, o óo sì kó wọn sinu àpótí náà.’
3 “Mo bá fi igi akasia kan àpótí kan, mo sì gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, mo gun orí òkè lọ pẹlu àwọn tabili náà lọ́wọ́ mi.
4 OLUWA bá kọ àwọn òfin mẹ́wàá tí ó kọ sí ara àwọn tabili àkọ́kọ́ sára àwọn tabili náà, ó sì kó wọn fún mi. Àwọn òfin mẹ́wàá yìí ni OLUWA sọ fun yín lórí òkè láti ààrin iná ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà.
5 Mo gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, mo sì kó àwọn tabili náà sinu àpótí tí mo kàn, wọ́n sì wà níbẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi.”
6 (Àwọn eniyan Israẹli rìn láti Beeroti Benejaakani lọ sí Mosera, ibẹ̀ ni Aaroni kú sí, tí wọ́n sì sin ín sí. Eleasari ọmọ rẹ̀ sì ń ṣe iṣẹ́ alufaa dípò rẹ̀.
7 Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ sí Gudigoda. Láti Gudigoda, wọ́n lọ sí Jotibata, ilẹ̀ tí ó kún fún ọpọlọpọ odò tí ń ṣàn.