Diutaronomi 13:4-10 BM

4 OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa tẹ̀lé, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù. Ẹ máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì máa gbọ́ tirẹ̀; ẹ máa sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.

5 Ṣugbọn pípa ni kí ẹ pa wolii tabi alálàá náà, nítorí pé ó ń kọ yín láti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú. Ẹ níláti pa olúwarẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ mú kí ẹ kọ ẹ̀yìn sí ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti là sílẹ̀ fun yín láti máa rìn, nítorí náà ẹ gbọdọ̀ yọ nǹkan burúkú náà kúrò láàrin yín.

6 “Bí ẹnikẹ́ni bá ń tàn ọ́ níkọ̀kọ̀ pé kí o lọ bọ oriṣa-koriṣa kan, tí ìwọ tabi àwọn baba rẹ kò bọ rí, olúwarẹ̀ kì báà jẹ́ arakunrin rẹ, tíí ṣe ọmọ ìyá rẹ, tabi ọmọ rẹ, lọkunrin tabi lobinrin, tabi aya rẹ, tí ó dàbí ẹyin ojú rẹ, tabi ọ̀rẹ́ rẹ tí o fẹ́ràn ju ẹ̀mí ara rẹ lọ;

7 oriṣa yìí kì báà jẹ́ èyí tí ó wà nítòsí, tí àwọn ará agbègbè yín ń bọ, tabi èyí tí ó jìnnà réré, tí àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ òkèèrè ń bọ.

8 O kò gbọdọ̀ gbọ́ tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ dá a lóhùn. O kò gbọdọ̀ ṣàánú fún un, o kò sì gbọdọ̀ bò ó.

9 Pípa ni kí o pa á, ìwọ gan-an ni kí o kọ́ sọ òkúta lù ú, kí àwọn eniyan yòókù tó kó òkúta bò ó.

10 Ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí tí ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde kúrò ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti.