Diutaronomi 17:2-8 BM

2 “Bí ọkunrin kan tabi obinrin kan láàrin àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín bá ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA Ọlọrun yín, nípa pé ó da majẹmu rẹ̀,

3 bí ó bá lọ bọ oriṣa, kì báà ṣe oòrùn, tabi òṣùpá, tabi ọ̀kan ninu àwọn nǹkan mìíràn tí ó wà ní ojú ọ̀run, tí mo ti pàṣẹ pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ;

4 bí wọn bá sọ fun yín tabi ẹ gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ìdánilójú sì wà pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní Israẹli,

5 ẹ mú ẹni tí ó ṣe ohun burúkú náà jáde lọ sí ẹnu ibodè yín, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

6 Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta kí wọ́n tó lè pa ẹnikẹ́ni fún irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ pa eniyan nítorí ẹ̀rí ẹnìkan ṣoṣo.

7 Àwọn ẹlẹ́rìí ni wọ́n gbọdọ̀ kọ́kọ́ sọ òkúta lu ẹni náà, lẹ́yìn náà ni gbogbo eniyan yóo tó kó òkúta bò ó, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.

8 “Bí ẹjọ́ kan bá ta kókó tí ó ní àríyànjiyàn ninu, tí ó sì ṣòro láti dá fún àwọn onídàájọ́ yín, kì báà jẹ mọ́ ṣíṣèèṣì paniyan ati mímọ̀ọ́nmọ̀ paniyan, tabi ẹ̀tọ́ lórí ohun ìní ẹni; tabi tí ẹnìkan bá ṣe ohun àbùkù kan sí ẹlòmíràn, ẹ óo lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín yóo yàn, pé kí ẹ ti máa jọ́sìn.