3 “Ohun tí yóo jẹ́ ti àwọn alufaa lára ẹran tí àwọn eniyan bá fi rúbọ nìyí, kì báà jẹ́ akọ mààlúù tabi aguntan ni wọ́n wá fi rúbọ, wọn yóo fún alufaa ní apá ati ẹ̀rẹ̀kẹ́ mejeeji, ati àpòlùkú rẹ̀.
4 Kí ẹ fún àwọn alufaa ní àkọ́so oko yín, ati àkọ́pọn ọtí waini yín, ati àkọ́ṣe òróró yín, ati irun aguntan tí ẹ bá kọ́kọ́ rẹ́.
5 Nítorí ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ẹ̀yà Lefi ati ti arọmọdọmọ wọn ni OLUWA Ọlọrun yín ti yàn láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún un.
6 “Bí ọ̀kan ninu ẹ̀yà Lefi bá dìde láti ilé rẹ̀, tabi ibikíbi tí ó wù kí ó ti wá ní Israẹli, tabi ìgbà yòówù tí ó bá fẹ́ láti wá sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìsìn rẹ̀,
7 ó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ níwájú OLUWA.
8 Bákan náà ni wọn yóo jọ pín oúnjẹ wọn láìka ohun tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá fi ranṣẹ sí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó kàn án ninu ogún baba rẹ̀ tí wọ́n tà.
9 “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń hù.