Diutaronomi 2:20-26 BM

20 (Ibẹ̀ ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ Refaimu, nítorí pé, àwọn Refaimu ni wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn ará Amoni a máa pè wọ́n ní Samsumimu.

21 Àwọn tí à ń pè ní Refaimu yìí pọ̀, wọ́n lágbára, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki, àwọn òmìrán. Ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run fún àwọn ará Amoni, wọ́n gba ilẹ̀ wọn, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ.

22 Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Esau tí wọn ń gbé òkè Seiri nígbà tí ó pa àwọn ará Hori run fún wọn, tí àwọn ọmọ Esau gba ilẹ̀ wọn, tí wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ títí di òní olónìí, ni ó ṣe fún àwọn ará Amoni.

23 Àwọn ará Afimu ni wọ́n ti ń gbé àwọn ìletò tí wọ́n wà títí dé Gasa tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn àwọn kan tí wọ́n wá láti Kafitori ni wọ́n pa wọ́n run, tí wọ́n sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ wọn.)

24 “Ẹ dìde, ẹ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yín, kí ẹ sì ré àfonífojì Anoni kọjá. Mo ti fi Sihoni, ọba Heṣiboni, ní ilẹ̀ àwọn ará Amori, le yín lọ́wọ́, àtòun ati ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bá a jagun, kí ẹ sì máa gba ilẹ̀ rẹ̀.

25 Láti òní lọ, n óo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé yìí, tí wọ́n bá gbúròó yín, wọn yóo máa gbọ̀n, ojora yóo sì mú wọn nítorí yín.

26 “Nítorí náà mo rán àwọn oníṣẹ́ láti aṣálẹ̀ Kedemotu, sí Sihoni, ọba Heṣiboni. Iṣẹ́ alaafia ni mo rán sí i, mo ní,