Diutaronomi 20:5-11 BM

5 “Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun yóo wí fún àwọn eniyan náà pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ilé titun, tí kò tíì yà á sí mímọ́? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo ya ilé rẹ̀ sí mímọ́.

6 Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbin ọgbà àjàrà, tí kò sì tíì jẹ ninu èso rẹ̀? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo jẹ èso ọgbà àjàrà rẹ̀.

7 Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ iyawo sọ́nà tí kò tíì gbé e wọlé? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo fẹ́ iyawo rẹ̀.’

8 “Àwọn ọ̀gágun yóo tún bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ẹ̀rù ń bà, tabi tí àyà rẹ̀ ń já? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé, kí ó má baà kó ojora bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.’

9 Nígbà tí àwọn ọ̀gágun bá parí ọ̀rọ̀ tí wọn ń bá àwọn eniyan náà sọ, wọn óo yan àwọn kan tí wọn óo máa ṣe aṣaaju ìsọ̀rí-ìsọ̀rí àwọn jagunjagun.

10 “Bí ẹ bá ti súnmọ́ ìlú tí ẹ fẹ́ bá jagun, ẹ kọ́ rán iṣẹ́ alaafia sí wọn.

11 Bí wọ́n bá rán iṣẹ́ alaafia pada, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn wọn fun yín, kí ẹ kó gbogbo àwọn ará ìlú náà lẹ́rú kí wọ́n sì máa sìn yín.