23 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ìyá aya rẹ̀ lòpọ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
24 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá pa aládùúgbò rẹ̀ níkọ̀kọ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
25 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa aláìṣẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
26 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí kò bá pa gbogbo àwọn òfin yìí mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’