1 Ìre tí Mose eniyan Ọlọrun sú fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú nìyí. Ó ní:
2 OLUWA wá láti orí òkè Sinai,ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu,ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani.Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́,ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.
3 Ọlọrun fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀,gbogbo àwọn tí a yà sọ́tọ̀ fún un wà lọ́wọ́ rẹ̀,nítorí náà ni wọ́n ṣe ń tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀,tí wọ́n sì ń gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀,
4 nígbà tí Mose bá fún wa ní òfin,tí ó jẹ́ ohun ìní gbogbo eniyan Israẹli.
5 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe di ọba ní Jeṣuruni,nígbà tí gbogbo àwọn olórí péjọ,àní, gbogbo àwọn olórí ninu ẹ̀yà Israẹli.
6 Mose súre fún ẹ̀yà Reubẹni, ó ní:“Ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ni, kò ní parun,àwọn eniyan rẹ̀ kò ní dínkù.”
7 Ó súre fún ẹ̀yà Juda pé:“OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀yà Juda,nígbà tí wọ́n bá pè fún ìrànwọ́,sì kó wọn pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn.Fi ọwọ́ ara rẹ jà fún wọn,sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ọ̀tá wọn.”