17 Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ dáradára, kí ẹ sì máa tẹ̀lé àwọn òfin ati àwọn ìlànà rẹ̀, tí ó fi lélẹ̀ fun yín.
18 Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó tọ́, ati ohun tí ó yẹ lójú OLUWA; kí ó lè dára fun yín, kí ẹ lè lọ gba ilẹ̀ dáradára tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín,
19 kí OLUWA lè lé àwọn ọ̀tá yín jáde fun yín, bí ó ti ṣèlérí.
20 “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́jọ́ iwájú pé, kí ni ìtumọ̀ àwọn ẹ̀rí ati ìlànà ati òfin tí OLUWA pa láṣẹ fun yín.
21 Ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘A ti jẹ́ ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ijipti rí, ṣugbọn agbára ni OLUWA fi kó wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.
22 Àwa pàápàá fi ojú wa rí i bí OLUWA ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí wọ́n bani lẹ́rù sí àwọn ará Ijipti ati sí Farao ọba wọn, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀.
23 OLUWA sì kó wa jáde, kí ó lè kó wa wá sí orí ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba wa.