18 Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú OLUWA bíi ti àkọ́kọ́, fún ogoji ọjọ́; n kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì mu, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti dá, tí ẹ ṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ẹ sì mú un bínú.
19 Nítorí inú tí OLUWA ń bí si yín ati inú rẹ̀ tí kò dùn sí yín bà mí lẹ́rù, nítorí ó ti ṣetán láti pa yín run. Ṣugbọn OLUWA tún gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà náà.
20 Inú bí OLUWA sí Aaroni tóbẹ́ẹ̀ tí OLUWA fi ṣetán láti pa á run, ṣugbọn mo gbadura fún Aaroni nígbà náà.
21 Mo bá gbé ère ọmọ mààlúù tí ẹ yá, tí ó jẹ́ ohun ẹ̀ṣẹ̀, mo dáná sun ún, mo lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, mo sì dà á sinu odò tí ń ṣàn wá láti orí òkè.
22 “Bẹ́ẹ̀ ni ẹ mú OLUWA bínú ní Tabera ati ní Masa, ati ni Kibiroti Hataafa.
23 Bákan náà ni ẹ ṣe ní Kadeṣi Banea, nígbà tí OLUWA ran yín lọ, tí ó ní kí ẹ lọ gba ilẹ̀ tí òun ti fi fun yín. Ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbà á gbọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀.
24 Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín, kò sí ìgbà kan tí ẹ kò ṣe orí kunkun sí OLUWA.