37 Bí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé orí èso tí eniyan fẹ́ gbìn, èso náà kò di aláìmọ́.
38 Ṣugbọn bí eniyan bá da omi lé èso náà lórí, tí apákan ninu òkú wọn sì já lé èso náà, ó di aláìmọ́ fun yín.
39 “Bí ọ̀kankan ninu àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
40 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ òkú ẹran náà níláti fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá ru òkú ẹran náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.
41 “Ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìríra, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ́.
42 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá ń fi àyà wọ́, tabi ohunkohun tí ó bá ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn tabi ohunkohun tí ó ní ọpọlọpọ ẹsẹ̀, tabi ohunkohun tí ó ń fà lórí ilẹ̀, nítorí ohun ìríra ni wọ́n.
43 Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di ìríra; ẹ kò gbọdọ̀ kó ẹ̀gbin bá ara yín, kí ẹ má baà di aláìmọ́.