18 O kò gbọdọ̀ fi ọmọ ìyá, tabi ọmọ baba iyawo rẹ ṣe aya níwọ̀n ìgbà tí aya rẹ tí í ṣe ẹ̀gbọ́n rẹ̀ bá wà láàyè.
19 “O kò gbọdọ̀ bá obinrin lòpọ̀, nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́.
20 O kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí o sì sọ ara rẹ di aláìmọ́ pẹlu rẹ̀.
21 O kò gbọdọ̀ fa èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ kalẹ̀ fún lílò níbi ìbọ̀rìṣà Moleki, kí o sì ti ipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọrun rẹ jẹ́. Èmi ni OLUWA.
22 O kò gbọdọ̀ bá ọkunrin lòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí obinrin, ohun ìríra ni.
23 O kò sì gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni obinrin kò sì gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀; ìwà burúkú ni.
24 “Má ṣe fi èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi ba ara rẹ jẹ́, nítorí pé, nǹkan wọnyi ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mò ń lé jáde kúrò níwájú yín fi ba ara wọn jẹ́.