4 Mose bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá.
5 Wọn sì ṣe é ní àṣáálẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ní aṣálẹ̀ Sinai. Àwọn eniyan náà ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fun wọn.
6 Ṣugbọn àwọn kan wà tí wọn kò lè bá wọn ṣe ọdún náà nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú. Wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni, wọ́n sì sọ fún wọn pé,
7 “Nítòótọ́, a ti di aláìmọ́ nítorí pé a fi ọwọ́ kan òkú, ṣugbọn kí ló dé tí a kò fi lè mú ọrẹ ẹbọ wa wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn arakunrin wa?”
8 Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró di ìgbà tí mo bá gbọ́ àṣẹ tí OLUWA yóo pa nípa yín.”
9 OLUWA bá sọ fún Mose pé,
10 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ọ̀kan ninu yín tabi àwọn ọmọ yín bá di aláìmọ́ nítorí pé ó fi ọwọ́ kan òkú; tabi ó wà ní ìrìn àjò, ṣugbọn tí ọkàn rẹ̀ sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá.