25 Ọlọrun si dá ẹranko ilẹ ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.
26 Ọlọrun si wipe, Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi irí wa: ki nwọn ki o si jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ, ati lori ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ.
27 Bẹ̃li Ọlọrun dá enia li aworan rẹ̀, li aworan Ọlọrun li o dá a; ati akọ ati abo li o dá wọn.
28 Ọlọrun si súre fun wọn. Ọlọrun si wi fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ki ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀; ki ẹ si ma jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ohun alãye gbogbo ti nrakò lori ilẹ.
29 Ọlọrun si wipe, kiye si i, Mo fi eweko gbogbo ti o wà lori ilẹ gbogbo ti nso eso fun nyin, ati igi gbogbo ninu eyiti iṣe igi eleso ti nso; ẹnyin ni yio ma ṣe onjẹ fun.
30 Ati fun gbogbo ẹranko ilẹ, ati fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ohun gbogbo ti o nrakò lori ilẹ, ti iṣe alaye, ni mo fi eweko tutu gbogbo fun li onjẹ: o si ri bẹ̃.
31 Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti o dá, si kiyesi i, daradara ni. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹfa.