Gẹn 10 YCE

Ìran Àwọn Ọmọ Noa

1 IRAN awọn ọmọ Noa ni wọnyi, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti: ati fun wọn li a si bí ọmọ lẹhin kíkun-omi.

2 Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi.

3 Ati awọn ọmọ Gomeri, Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togarma.

4 Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu.

5 Lati ọdọ awọn wọnyi li a ti pín erekuṣu awọn orilẹ-ède ni ilẹ wọn, olukuluku gẹgẹ bi ohùn rẹ̀; gẹgẹ bi idile wọn, li orilẹ-ède wọn.

6 Ati awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, ati Futi, ati Kenaani.

7 Ati awọn ọmọ Kuṣi; Seba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka; ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba, ati Dedani.

8 Kuṣi si bí Nimrodu: on si bẹ̀rẹ si idi alagbara li aiye.

9 On si ṣe ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA: nitori na li a ṣe nwipe, Gẹgẹ bi Nimrodu ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA.

10 Ipilẹṣẹ ijọba rẹ̀ ni Babeli, ati Ereki, ati Akkadi, ati Kalne, ni ilẹ Ṣinari.

11 Lati ilẹ na ni Aṣṣuri ti jade lọ, o si tẹ̀ Ninefe, ati ilu Rehoboti, ati Kala dó.

12 Ati Reseni lagbedemeji Ninefe on Kala: eyi na ni ilu nla.

13 Misraimu si bí Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu,

14 Ati Patrusimu, ati Kasluhimu (lati ọdọ ẹniti Filistimu ti wá), ati Kaftorimu.

15 Kenaani si bí Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti,

16 Ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi,

17 Ati awọn ara Hiffi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini,

18 Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati; lẹhin eyini ni idile awọn ara Kenaani tàn kalẹ.

19 Ati àgbegbe awọn ara Kenaani ni Sidoni, bi o ti mbọ̀wa Gerari, titi de Gasa; bi o ti nlọ si Sodomu, ati Gomorra, ati Adma, ati Seboimu, titi dé Laṣa.

20 Awọn wọnyi li ọmọ Hamu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, ati li orilẹ-ède wọn.

21 Fun Ṣemu pẹlu, baba gbogbo awọn ọmọ Eberi, ẹgbọn Jafeti ati fun on li a bimọ.

22 Awọn ọmọ Ṣemu: Elamu, ati Aṣṣuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu.

23 Ati awọn ọmọ Aramu; Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Maṣi.

24 Arfaksadi si bí Ṣela; Ṣela si bí Eberi.

25 Ati fun Eberi li a bí ọmọkunrin meji; orukọ ekini ni Pelegi; nitori nigba ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ yà; orukọ arakunrin rẹ̀ ni Joktani.

26 Joktani si bí Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera,

27 Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla,

28 Ati Obali, ati Abimaeli, ati Ṣeba,

29 Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu: gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Joktani.

30 Ibugbe wọn si ti Meṣa lọ, bi iwọ ti nlọ si Sefari, oke kan ni ìla-õrùn.

31 Awọn wọnyi li ọmọ Ṣemu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, li orilẹ-ède wọn.

32 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Noa, gẹgẹ bi iran wọn, li orilẹ-ède wọn: lati ọwọ́ awọn wọnyi wá li a ti pín orilẹ-ède aiye lẹhin kíkun-omi.