Gẹn 21 YCE

A Bí Isaaki

1 OLUWA si bẹ̀ Sara wò bi o ti wi, OLUWA si ṣe fun Sara bi o ti sọ.

2 Sara si loyun, o si bí ọmọkunrin kan fun Abrahamu li ogbologbo rẹ̀, li akokò igbati Ọlọrun dá fun u.

3 Abrahamu si pè orukọ ọmọ rẹ̀ ti a bí fun u, ni Isaaki, ẹniti Sara bí fun u.

4 Abrahamu si kọ Isaaki ọmọ rẹ̀ ni ilà, nigbati o di ọmọ ijọ́ mẹjọ, gẹgẹ bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u.

5 Abrahamu si jẹ ẹni ọgọrun ọdún, nigbati a bí Isaaki ọmọ rẹ̀ fun u.

6 Sara si wipe, Ọlọrun pa mi lẹrin; gbogbo ẹniti o gbọ́ yio si rẹrin pẹlu mi.

7 O si wipe, Tani iba wi fun Abrahamu pe, Sara yio fi ọmú fun ọmọ mu? mo sá bí ọmọ kan fun u li ogbologbo rẹ̀.

8 Ọmọ na si dàgba, a si já a li ẹnu ọmú: Abrahamu si sè àse nla li ọjọ́ na ti a já Isaaki li ẹnu ọmú.

Wọ́n Lé Hagari ati Iṣimaeli Jáde nílé

9 Sara si ri ọmọ Hagari, ara Egipti, ti o bí fun Abrahamu, o nfi i rẹrin.

10 Nitorina li o ṣe wi fun Abrahamu pe, Lé ẹrubirin yi jade ti on ti ọmọ rẹ̀: nitoriti ọmọ ẹrubirin yi ki yio ṣe arole pẹlu Isaaki, ọmọ mi.

11 Ọrọ yi si buru gidigidi li oju Abrahamu nitori ọmọ rẹ̀.

12 Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Máṣe jẹ ki o buru li oju rẹ nitori ọmọdekunrin na, ati nitori ẹrubirin rẹ; ni gbogbo eyiti Sara sọ fun ọ, fetisi ohùn rẹ̀; nitori ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ.

13 Ati ọmọ ẹrubirin na pẹlu li emi o sọ di orilẹ-ède, nitori irú-ọmọ rẹ ni iṣe.

14 Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o mu àkara ati ìgo omi kan, o fi fun Hagari, o gbé e lé e li ejika, ati ọmọ na, o si lé e jade: on si lọ, o nrìn kakiri ni ijù Beer-ṣeba.

15 Omi na si tán ninu ìgo, o si sọ̀ ọmọ na si abẹ ìgboro kan.

16 O si lọ, o joko kọju si i, li ọ̀na jijìn rére, o tó bi itafasi kan: nitori ti o wipe, Ki emi má ri ikú ọmọ na. O si joko kọju si i, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o nsọkun.

17 Ọlọrun si gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na: angeli Ọlọrun si pè Hagari lati ọrun wá, o bi i pe, Kili o ṣe ọ, Hagari? máṣe bẹ̀ru; nitori ti Ọlọrun ti gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na nibiti o gbé wà.

18 Dide, gbé ọmọdekunrin na, ki o si dì i mu; nitori ti emi o sọ ọ di orilẹ-ède nla.

19 Ọlọrun si ṣí i li oju, o si ri kanga omi kan; o lọ, o si pọnmi kún ìgo na, o si fi fun ọmọdekunrin na mu.

20 Ọlọrun si wà pẹlu ọmọdekunrin na; o si dàgba, o si joko ni ijù, o di tafatafa.

21 O si joko ni ijù Parani: iya rẹ̀ si fẹ́ obinrin fun u lati ilẹ Egipti wá.

Majẹmu láàrin Abrahamu ati Abimeleki

22 O si ṣe li akokò na, ni Abimeleki ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, wi fun Abrahamu pe, Ọlọrun pẹlu rẹ ni gbogbo ohun ti iwọ nṣe.

23 Njẹ nisisiyi fi Ọlọrun bura fun mi nihinyi pe iwọ ki yio ṣe ẹ̀tan si mi, tabi si ọmọ mi, tabi si ọmọ-ọmọ mi: ṣugbọn gẹgẹ bi iṣeun ti mo ṣe si ọ, bẹ̃ni iwọ o si ṣe si mi, ati si ilẹ ti iwọ ti ṣe atipo ninu rẹ̀.

24 Abrahamu si wipe, emi o bura.

25 Abrahamu si ba Abimeleki wi nitori kanga omi kan, ti awọn ọmọ-ọdọ Abimeleki fi agbara gbà.

26 Abimeleki si wipe, emi kò mọ̀ ẹniti o ṣe nkan yi: bẹ̃ni iwọ kò sọ fun mi, bẹ̃li emi kò gbọ́, bikoṣe loni.

27 Abrahamu si mu agutan, ati akọmalu, o fi wọn fun Abimeleki; awọn mejeji si dá majẹmu.

28 Abrahamu si yà abo ọdọ-agutan meje ninu agbo si ọ̀tọ fun ara wọn.

29 Abimeleki si bi Abrahamu pe, kili a le mọ̀ abo ọdọ-agutan meje ti iwọ yà si ọ̀tọ fun ara wọn yi si?

30 O si wipe, nitori abo ọdọ-agutan meje yi ni iwọ o gbà lọwọ mi, ki nwọn ki o le ṣe ẹrí mi pe, emi li o wà kanga yi.

31 Nitorina li o ṣe pè ibẹ̀ na ni Beer-ṣeba; nitori nibẹ̀ li awọn mejeji gbé bura.

32 Bẹ̃ni nwọn si dá majẹmu ni Beer-ṣeba: nigbana li Abimeleki dide, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilẹ awọn ara Filistia.

33 Abrahamu si lọ́ igi tamariski kan ni Beer-ṣeba, nibẹ̀ li o si pè orukọ OLUWA, Ọlọrun Aiyeraiye.

34 Abrahamu si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọjọ́ pupọ̀.