Gẹn 37 YCE

Josẹfu ati Àwọn Arakunrin Rẹ̀

1 JAKOBU si joko ni ilẹ ti baba rẹ̀ ti ṣe atipo, ani ilẹ Kenaani.

2 Wọnyi ni iran Jakobu. Nigbati Josefu di ẹni ọdún mẹtadilogun, o nṣọ́ agbo-ẹran pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; ọmọde na si wà pẹlu awọn ọmọ Bilha, ati pẹlu awọn ọmọ Silpa, awọn aya baba rẹ̀; Josefu si mú ihin buburu wọn wá irò fun baba wọn.

3 Israeli si fẹ́ Josefu jù gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ lọ, nitori ti iṣe ọmọ ogbó rẹ̀; o si dá ẹ̀wu alarabara aṣọ fun u.

4 Nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ri pe baba wọn fẹ́ ẹ jù gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn korira rẹ̀, nwọn kò si le sọ̀rọ si i li alafia.

5 Josefu si lá alá kan, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀; nwọn si tun korira rẹ̀ si i.

6 O si wi fun wọn pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ gbọ́ alá yi ti mo lá.

7 Sa wò o, awa nyí ití li oko, si wò o, ití mi dide, o si duro ṣanṣan; si wò o, ití ti nyin dide duro yiká, nwọn si ntẹriba fun ití mi.

8 Awọn arakunrin rẹ̀ si wi fun u pe, Iwọ o ha jọba lori wa bi? tabi iwọ o ṣe olori wa nitõtọ? nwọn si tun korira rẹ̀ si i nitori alá rẹ̀ ati nitori ọ̀rọ rẹ̀.

9 O si tun lá alá miran, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀, o wipe, Sa wò o, mo tun lá alá kan si i; si wò o, õrùn, ati oṣupa, ati irawọ mọkanla nforibalẹ fun mi.

10 O si rọ́ ọ fun baba rẹ̀, ati fun awọn arakunrin rẹ̀: baba rẹ̀ si bá a wi, o si wi fun u pe, Alá kili eyi ti iwọ lá yi? emi ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ yio ha wá nitõtọ, lati foribalẹ fun ọ bi?

11 Awọn arakunrin rẹ̀ si ṣe ilara rẹ̀; ṣugbọn baba rẹ̀ pa ọ̀rọ na mọ́.

Wọ́n Ta Josẹfu Lẹ́rú sí Ijipti

12 Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ lati bọ́ agbo-ẹran baba wọn ni Ṣekemu.

13 Israeli si wi fun Josefu pe, Ni Ṣekemu ki awọn arakunrin rẹ gbé mbọ́ ẹran? wá, emi o si rán ọ si wọn. On si wi fun u pe, Emi niyi.

14 O si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, lọ wò alafia awọn arakunrin rẹ, ati alafia awọn agbo-ẹran; ki o si mú ihin pada fun mi wá. Bẹ̃li o si rán a lati afonifoji Hebroni lọ, on si dé Ṣekemu.

15 Ọkunrin kan si ri i, si wò o, o nrìn kakiri ni pápa: ọkunrin na si bi i pe, Kini iwọ nwá?

16 On si wipe, Emi nwá awọn arakunrin mi: mo bẹ̀ ọ, sọ ibi ti nwọn gbé mbọ́ agbo-ẹran wọn fun mi.

17 Ọkunrin na si wipe, Nwọn ti lọ kuro nihin; nitori mo gbọ́, nwọn nwipe, ẹ jẹ ki a lọ si Dotani. Josefu si lepa awọn arakunrin rẹ̀, o si ri wọn ni Dotani.

18 Nigbati nwọn si ri i lokere; ki o tilẹ to sunmọ eti ọdọ wọn, nwọn di rikiṣi si i lati pa a.

19 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Wò o, alála nì mbọ̀wá.

20 Nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si wọ́ ọ sọ sinu ọkan ninu ihò wọnyi, awa o si wipe ẹranko buburu li o pa a jẹ: awa o si ma wò bi alá rẹ̀ yio ti ri.

21 Reubeni si gbọ́, o si gbà a li ọwọ́ won; o si wipe, Ẹ máṣe jẹ ki a gbà ẹmi rẹ̀.

22 Reubeni si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe ta ẹ̀jẹ, ṣugbọn ẹ sọ ọ sinu ihò yi ti mbẹ li aginjù, ki ẹ má si fọwọkàn a; nitori ki o ba le gbà a lọwọ wọn lati mú u pada tọ̀ baba rẹ̀ lọ.

23 O si ṣe nigbati Josefu dé ọdọ awọn arakunrin rẹ̀, nwọn bọ́ ẹ̀wu Josefu, ẹ̀wu alarabara aṣọ ti o wà lara rẹ̀;

24 Nwọn si mú u, nwọn si gbe e sọ sinu ihò kan: ihò na si gbẹ, kò li omi.

25 Nwọn si joko lati jẹun: nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn si wò, si kiyesi i, ọwọ́-èro ara Iṣmaeli nti Gileadi bọ̀; ti awọn ti ibakasiẹ ti o rù turari ati ikunra ati ojia, nwọn nmú wọn lọ si Egipti.

26 Judah si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ere ki li o jẹ́ bi awa ba pa arakunrin wa, ti a si bò ẹ̀jẹ rẹ̀?

27 Ẹ wá ẹ jẹ ki a tà a fun awọn ara Iṣmaeli ki a má si fọwọ wa kàn a; nitori arakunrin wa ati ara wa ni iṣe. Awọn arakunrin rẹ̀ si gbà tirẹ̀.

28 Nigbana li awọn oniṣòwo ara Midiani nkọja lọ; nwọn si fà a, nwọn si yọ Josefu jade ninu ihò, nwọn si tà Josefu li ogún owo fadaka: nwọn si mú Josefu lọ si Egipti.

29 Reubeni si pada lọ si ihò; si wò o, Josefu kò sí ninu ihò na; o si fà aṣọ rẹ̀ ya.

30 O si pada tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wipe, Ọmọde na kò sí; ati emi, nibo li emi o gbé wọ̀?

31 Nwọn si mú ẹ̀wu Josefu, nwọn si pa ọmọ ewurẹ kan, nwọn si rì ẹ̀wu na sinu ẹ̀jẹ na.

32 Nwọn si fi ẹ̀wu alarabara aṣọ na ranṣẹ, nwọn si mú u tọ̀ baba wọn wá; nwọn si wipe, Eyi li awa ri: mọ̀ nisisiyi bi ẹ̀wu ọmọ rẹ ni, bi on kọ́.

33 On si mọ̀ ọ, o si wipe, Ẹ̀wu ọmọ mi ni; ẹranko buburu ti pa a jẹ; li aiṣe aniani, a ti fà Josefu ya pẹrẹpẹrẹ.

34 Jakobu si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si ṣọ̀fọ ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ pupọ̀.

35 Ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ obinrin dide lati ṣìpẹ fun u; ṣugbọn o kọ̀ lati gbipẹ̀; o si wipe, Ninu ọ̀fọ li emi o sa sọkalẹ tọ̀ ọmọ mi lọ si isà-okú. Bayi ni baba rẹ̀ sọkun rẹ̀.

36 Awọn ara Midiani si tà a si Egipti fun Potifari, ijoye Farao kan, ati olori ẹṣọ́.