1 LẸHIN nkan wọnyi ọ̀rọ OLUWA tọ̀ Abramu wá li ojuran, wipe, Má bẹ̀ru, Abramu; Emi li asà rẹ, ère nla rẹ gidigidi.
2 Abramu si wipe, OLUWA Ọlọrun, kini iwọ o fi fun mi, emi sa nlọ li ailọmọ, Elieseri ti Damasku yi si ni ẹniti o ni ile mi?
3 Abramu si wipe, Wo o emi ni iwọ kò fi irú-ọmọ fun: si wo o, ẹrú ti a bi ni ile mi ni yio jẹ arolé.
4 Si wo o, ọ̀rọ OLUWA tọ̀ ọ wá, wipe, Eleyi ki yio ṣe arole rẹ; bikoṣe ẹniti yio ti inu ara rẹ jade, on ni yio ṣe arole rẹ.
5 O si mu u jade wá si gbangba, o si wi pe, Gboju wò oke ọrun nisisiyi, ki o si kà irawọ bi iwọ ba le kà wọn: o si wi fun u pe, Bẹ̃ni irú-ọmọ rẹ yio ri.
6 O si gba OLUWA gbọ́; on si kà a si fun u li ododo.
7 O si wi fun u pe, Emi li OLUWA ti o mu ọ jade lati Uri ti Kaldea wá, lati fi ilẹ yi fun ọ lati jogun rẹ̀.
8 O si wipe, OLUWA Ọlọrun, nipa bawo li emi o fi mọ̀ pe emi o jogun rẹ̀?
9 O si wi fun u pe, Mu ẹgbọrọ malu ọlọdun mẹta fun mi wá, ati ewurẹ ọlọdun mẹta, ati àgbo ọlọdun mẹta, ati oriri kan, ati ọmọ ẹiyẹle kan.
10 O si mu gbogbo nkan wọnyi wá sọdọ rẹ̀, o si là wọn li agbedemeji, o si fi ẹ̀la ekini kọju si ekeji: bikoṣe awọn ẹiyẹ ni kò là.
11 Nigbati awọn ẹiyẹ si sọkalẹ wá si ori okú wọnyi, Abramu lé wọn kuro.
12 O si ṣe nigbati õrùn nwọ̀ lọ, orun ìjika kùn Abramu; si kiyesi i, ẹ̀ru bà a, òkunkun biribiri si bò o.
13 On si wi fun Abramu pe, Mọ̀ nitõtọ pe irú-ọmọ rẹ yio ṣe alejo ni ilẹ ti ki iṣe ti wọn, nwọn o si sìn wọn, nwọn o si jẹ wọn ni íya ni irinwo ọdún;
14 Ati orilẹ-ède na pẹlu ti nwọn o ma sìn, li emi o dá lẹjọ: lẹhin na ni nwọn o si jade ti awọn ti ọrọ̀ pipọ̀.
15 Iwọ o si tọ̀ awọn baba rẹ lọ li alafia; li ogbologbo ọjọ́ li a o sin ọ.
16 Ṣugbọn ni iran kẹrin, nwọn o si tun pada wá nihinyi: nitori ẹ̀ṣẹ awọn ara Amori kò ti ikún.
17 O si ṣe nigbati õrùn wọ̀, òkunkun si ṣú, kiyesi i ileru elẽfin, ati iná fitila ti nkọja lãrin ẹ̀la wọnni.
18 Li ọjọ́ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu pe, irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate:
19 Awọn enia Keni, ati awọn enia Kenissi, ati awọn enia Kadmoni,
20 Ati awọn enia Hitti, ati awọn enia Perissi, ati awọn Refaimu,
21 Ati awọn enia Amori, ati awọn enia Kenaani, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Jebusi.