Gẹn 44 YCE

Ife Tí Ó Sọnù

1 O SI fi aṣẹ fun iriju ile rẹ̀, wipe, Fi onjẹ kún inu àpo awọn ọkunrin wọnyi, ìwọn ti nwọn ba le rù, ki o si fi owo olukuluku si ẹnu àpo rẹ̀.

2 Ki o si fi ago mi, ago fadaka nì, si ẹnu àpo abikẹhin, ati owo ọkà rẹ̀. O si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ ti Josefu ti sọ.

3 Bi ojúmọ si ti mọ́, a si rán awọn ọkunrin na lọ, awọn ati awọn kẹtẹkẹtẹ wọn.

4 Nigbati nwọn si jade kuro ni ilu na, ti nwọn kò si jìna, Josefu wi fun iriju rẹ̀ pe, Dide, lepa awọn ọkunrin na; nigbati iwọ ba si bá wọn, wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi fi buburu san rere?

5 Ninu eyi ki oluwa mi ima mu, eyiti o si fi nmọ̀ran? ẹnyin ṣe buburu li eyiti ẹnyin ṣe yi.

6 O si lé wọn bá, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn.

7 Nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti oluwa mi fi sọ irú ọ̀rọ wọnyi? Ki a má ri pe awọn ọmọ-ọdọ rẹ ṣe bi irú nkan wọnyi.

8 Kiyesi i, owo ti awa ri li ẹnu àpo wa, awa si tun mú pada fun ọ lati ilẹ Kenaani wá: bawo li awa o ṣe jí fadaka tabi wurà ninu ile oluwa rẹ?

9 Lọdọ ẹnikẹni ninu awọn iranṣẹ rẹ ti a ba ri i, ki o kú, ati awa pẹlu ki a di ẹrú oluwa mi.

10 O si wipe, Njẹ ki o si ri bẹ̃ gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin: ẹniti a ba ri i li ọwọ́ rẹ̀ on ni yio di ẹrú mi, ẹnyin o si ṣe alailẹṣẹ.

11 Nigbana ni olukuluku nwọn yara sọ̀ àpo rẹ̀ kalẹ, olukuluku nwọn si tú àpo rẹ̀.

12 O si nwá a kiri, o bẹ̀rẹ lati ẹgbọ́n wá, o si pin lọdọ abikẹhin: a si ri ago na ninu àpo Benjamini.

13 Nigbana ni nwọn fà aṣọ wọn ya olukuluku si dì ẹrù lé kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilu.

14 Ati Judah ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si ile Josefu; on sa wà nibẹ̀: nwọn si wolẹ niwaju rẹ̀.

15 Josefu si wi fun wọn pe, Iwa kili eyiti ẹnyin hù yi? ẹnyin kò mọ̀ pe irú enia bi emi a ma mọ̀ran nitõtọ?

16 Judah si wipe, Kili a o wi fun oluwa mi? kili a o fọ̀? tabi awa o ti ṣe wẹ̀ ara wa mọ́? Ọlọrun ti hú ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jade: wò o, awa di ẹrú oluwa mi, ati awa, ati ẹniti a ri ago na li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu.

17 On si wipe, Ki a má ri pe emi o ṣe bẹ̃: ṣugbọn ọkunrin na li ọwọ́ ẹniti a ri ago na, on ni yio ṣe ẹrú mi; bi o ṣe ti ẹnyin, ẹ goke tọ̀ baba nyin lọ li alafia.

Juda Bẹ̀bẹ̀ fún Ìdásílẹ̀ Bẹnjamini

18 Nigbana ni Judah sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o sọ gbolohùn ọ̀rọ kan li eti oluwa mi, ki o máṣe binu si iranṣẹ rẹ; bi Farao tikalarẹ̀ ni iwọ sá ri.

19 Oluwa mi bère lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, wipe, Ẹnyin ní baba, tabi arakunrin bi?

20 Awa si wi fun oluwa mi pe, Awa ní baba, arugbo, ati ọmọ kan li ogbologbo rẹ̀, abikẹhin; arakunrin rẹ̀ si kú, on nikanṣoṣo li o si kù li ọmọ iya rẹ̀, baba rẹ̀ si fẹ́ ẹ.

21 Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Mú u sọkalẹ tọ̀ mi wá, ki emi ki o le fi oju mi kàn a.

22 Awa si wi fun oluwa mi pe, Ọdọmọde na kò le fi baba rẹ̀ silẹ: nitoripe bi o ba fi i silẹ, baba rẹ̀ yio kú.

23 Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Ayaṣebi arakunrin nyin abikẹhin ba bá nyin sọkalẹ wá, ẹnyin ki yio ri oju mi mọ́.

24 O si ṣe nigbati awa goke tọ̀ baba mi iranṣẹ rẹ lọ, awa sọ̀rọ oluwa mi fun u.

25 Baba wa si wipe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá.

26 Awa si wipe, Awa kò le sọkalẹ lọ: bi arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa, njẹ awa o sọkalẹ lọ; nitori ti awa ki o le ri oju ọkunrin na, bikoṣepe arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa.

27 Baba mi iranṣẹ rẹ si wi fun wa pe Ẹnyin mọ̀ pe aya mi bí ọmọ meji fun mi:

28 Ọkan si ti ọdọ mi jade lọ, mo si wipe, Nitõtọ a fà a ya pẹrẹpẹrẹ; emi kò si ri i lati igbana wá:

29 Bi ẹnyin ba si mú eyi lọ lọwọ mi pẹlu, ti ibi kan si ṣe e, ibinujẹ li ẹnyin o fi mú ewú mi lọ si isà-okú.

30 Njẹ nisisiyi, nigbati mo ba dé ọdọ baba mi, iranṣẹ rẹ, ti ọmọde na kò si wà pẹlu wa; bẹ̃ni ẹmi rẹ̀ dìmọ́ ẹmi ọmọde na;

31 Yio si ṣe, bi o ba ri pe ọmọde na kò pẹlu wa, yio kú: awọn iranṣẹ rẹ yio si fi ibinujẹ mú ewú baba wa iranṣẹ rẹ lọ si isà-okú.

32 Nitori iranṣẹ rẹ li o ṣe onigbọwọ ọmọde na fun baba mi wipe, Bi emi kò ba mú u tọ̀ ọ wá, emi ni o gbà ẹbi na lọdọ baba mi lailai.

33 Njẹ nisisiyi emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o joko ni ipò ọmọde na li ẹrú fun oluwa mi; ki o si jẹ ki ọmọde na ki o bá awọn arakunrin rẹ̀ goke lọ.

34 Nitori bi bawo li emi o fi goke tọ̀ baba mi lọ ki ọmọde na ki o ma wà pẹlu mi? ki emi má ba ri ibi ti mbọ̀wá bá baba mi.