1 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi ni Ọlọrun dan Abrahamu wò, o si wi fun u pe, Abrahamu: on si dahùn pe, Emi niyi.
2 O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ.
3 Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãrì, o si mu meji ninu awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati Isaaki, ọmọ rẹ̀, o si là igi fun ẹbọ sisun na, o si dide, o si lọ si ibi ti Ọlọrun sọ fun u.
4 Ni ijọ́ kẹta Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o ri ibẹ̀ na li okere.
5 Abrahamu si wi fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, pe, Ẹnyin joko nihin pẹlu kẹtẹkẹtẹ; ati emi ati ọmọ yi yio lọ si ọhùn ni, a o si gbadura, a o si tun pada tọ̀ nyin wá.
6 Abrahamu si mu igi ẹbọ sisun na, o si dì i rù Isaaki, ọmọ rẹ̀; o si mu iná li ọwọ́ rẹ̀, ati ọbẹ; awọn mejeji si jùmọ nlọ.
7 Isaaki si sọ fun Abrahamu baba rẹ̀, o si wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi, ọmọ mi. On si wipe, Wò iná on igi; ṣugbọn nibo li ọdọ-agutan ẹbọ sisun na gbé wà?
8 Abrahamu si wipe, Ọmọ mi, Ọlọrun tikalarẹ̀ ni yio pèse ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun: bẹ̃li awọn mejeji jùmọ nlọ.
9 Nwọn si de ibi ti Ọlọrun ti wi fun u; Abrahamu si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si to igi rere, o si dì Isaaki ọmọ rẹ̀, o si dá a bulẹ li ori pẹpẹ lori igi na.
10 Abrahamu si nawọ rẹ̀, o si mu ọbẹ na lati dúmbu ọmọ rẹ̀.
11 Angeli OLUWA nì si kọ si i lati ọrun wá, o wipe, Abrahamu, Abrahamu: o si dahùn pe, Emi niyi.
12 O si wipe, Máṣe fọwọkàn ọmọde nì, bẹ̃ni iwọ kó gbọdọ ṣe e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ̀ pe iwọ bẹ̀ru Ọlọrun, nigbati iwọ kò ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo.
13 Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, lẹhin rẹ̀, àgbo kan ti o fi iwo rẹ̀ há ni pantiri: Abrahamu si lọ o mu àgbo na, o si fi i rubọ sisun ni ipò ọmọ rẹ̀.
14 Abrahamu si pè orukọ ibẹ̀ na ni Jehofajire: bi a ti nwi titi di oni yi, Li oke OLUWA li a o gbé ri i.
15 Angeli OLUWA nì si kọ si Abrahamu lati ọrun wá lẹrinkeji,
16 O si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, li OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo:
17 Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn;
18 Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ́.
19 Abrahamu si pada tọ̀ awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, nwọn si dide, nwọn si jùmọ lọ si Beer-ṣeba; Abrahamu si joko ni Beer-ṣeba.
20 O si ṣe, lẹhin nkan wọnyi, li a sọ fun Abrahamu pe, kiyesi i, Milka, on pẹlu si ti bimọ fun Nahori, arakunrin rẹ;
21 Husi akọ́bi rẹ̀, ati Busi arakunrin rẹ̀, ati Kemueli baba Aramu.
22 Ati Kesedi, ati Haso, ati Pildaṣi, ati Jidlafu, ati Betueli.
23 Betueli si bí Rebeka: awọn mẹjọ yi ni Milka bí fun Nahori, arakunrin Abrahamu.
24 Ati àle rẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ Rehuma, on pẹlu si bí Teba, ati Gahamu, ati Tahaṣi, ati Maaka.