1 NIGBATI Rakeli ri pe on kò bimọ fun Jakobu, Rakeli ṣe ilara arabinrin rẹ̀; o si wi fun Jakobu pe, Fun mi li ọmọ, bikoṣe bẹ̃ emi o kú.
2 Jakobu si binu si Rakeli: o si wipe, Emi ha wà ni ipò Ọlọrun, ẹniti o dù ọ li ọmọ bíbi?
3 On si wipe, Wò Bilha iranṣẹbinrin mi, wọle tọ̀ ọ; on ni yio si bí lori ẽkun mi, ki a le gbé mi ró pẹlu nipasẹ rẹ̀.
4 O si fi Bilha, iranṣẹbinrin rẹ̀, fun u li aya: Jakobu si wọle tọ̀ ọ.
5 Bilha si yún, o si bí ọmọkunrin kan fun Jakobu.
6 Rakeli si wipe, Ọlọrun ti ṣe idajọ mi, o si ti gbọ́ ohùn mi, o si fi ọmọkunrin kan fun mi pẹlu: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Dani.
7 Bilha, iranṣẹbinrin Rakeli, si tun yún, o si bi ọmọkunrin keji fun Jakobu.
8 Rakeli si wipe, Ijakadi nla ni mo fi bá arabinrin mi ja, emi si dá a: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Naftali.
9 Nigbati Lea ri pe on dẹkun ọmọ bíbi, o si mú Silpa, iranṣẹbinrin rẹ̀, o si fi i fun Jakobu li aya.
10 Silpa, iranṣẹbinrin Lea, si bí ọmọkunrin kan fun Jakobu.
11 Lea si wipe, Ire de: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gadi.
12 Silpa iranṣẹbinrin Lea si bí ọmọkunrin keji fun Jakobu.
13 Lea si wipe, Alabukún fun li emi, nitori ti awọn ọmọbinrin yio ma pè mi li alabukún fun: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Aṣeri.
14 Li akokò ìgba ikore alikama, Reubeni si lọ, o si ri eso mandraki ni igbẹ́, o si mú wọn fun Lea iya rẹ̀ wá ile. Nigbana ni Rakeli wi fun Lea pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi ninu mandraki ọmọ rẹ.
15 O si wi fun u pe, Iṣe nkan kekere ti iwọ gbà ọkọ lọwọ mi? iwọ si nfẹ́ gbà mandraki ọmọ mi pẹlu? Rakeli si wipe, Nitori na ni yio ṣe sùn tì ọ li alẹ yi nitori mandraki ọmọ rẹ.
16 Jakobu si ti inu oko dé li aṣalẹ, Lea si jade lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Iwọ kò le ṣe aima wọle tọ̀ mi wá, nitori ti emi ti fi mandraki ọmọ mi bẹ̀ ọ li ọ̀wẹ. On si sùn tì i li oru na.
17 Ọlọrun si gbọ́ ti Lea, o si yún, o si bí ọmọkunrin karun fun Jakobu.
18 Lea si wipe, Ọlọrun san ọ̀ya mi fun mi, nitori ti mo fi iranṣẹbinrin mi fun ọkọ mi; o si pè orukọ rẹ̀ ni Issakari.
19 Lea si tun yún, o si bí ọmọkunrin kẹfa fun Jakobu.
20 Lea si wipe, Ọlọrun ti fun mi li ẹ̀bun rere; nigbayi li ọkọ mi yio tó ma bá mi gbé, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹfa fun u: o si pè orukọ rẹ̀ ni Sebuluni.
21 Nikẹhin rẹ̀ li o si bí ọmọbinrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Dina.
22 Ọlọrun si ranti Rakeli, Ọlọrun si gbọ́ tirẹ̀, o si ṣí i ni inu.
23 O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Ọlọrun mú ẹ̀gan mi kuro:
24 O si pè orukọ rẹ̀ ni Josefu; o si wipe, Ki OLUWA ki o fi ọmọkunrin kan kún u fun mi pẹlu.
25 O si ṣe, nigbati Rakeli bí Josefu tán, Jakobu si wi fun Labani pe, Rán mi jade lọ, ki emi ki o le ma lọ si ibiti mo ti wá, ati si ilẹ mi.
26 Fun mi li awọn obinrin mi, ati awọn ọmọ mi, nitori awọn ẹniti mo ti nsìn ọ, ki o si jẹ ki nma lọ: iwọ sá mọ̀ ìsin ti mo sìn ọ.
27 Labani si wipe, Duro, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, joko: nitori ti mo ri i pe, OLUWA ti bukún fun mi nitori rẹ.
28 O si wi fun u pe, Sọ iye owo iṣẹ rẹ, emi o si fi fun ọ.
29 O si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ bi emi ti sìn ọ, ati bi ẹran-ọ̀sin rẹ ti wà lọdọ mi.
30 Diẹ ni iwọ sá ti ní ki nto dé ọdọ rẹ, OLUWA si busi i li ọ̀pọlọpọ fun ọ lati ìgba ti mo ti dé: njẹ nisisiyi nigbawo li emi o pèse fun ile mi?
31 O si bi i pe, Kili emi o fi fun ọ? Jakobu si wi pe, Iwọ máṣe fun mi li ohun kan: bi iwọ o ba le ṣe eyi fun mi, emi o ma bọ́, emi o si ma ṣọ́ agbo-ẹran rẹ.
32 Emi o là gbogbo agbo-ẹran rẹ já loni, emi o mú gbogbo ẹran abilà ati alamì kuro nibẹ̀, ati gbogbo ẹran pupa rúsurusu kuro ninu awọn agutan, ati gbogbo ẹran alamì ati abilà ninu awọn ewurẹ: eyi ni yio si ma ṣe ọ̀ya mi.
33 Ododo mi yio si jẹ mi li ẹrí li ẹhin-ọla nigbati iwọ o wá wò ọ̀ya mi: gbogbo eyiti kò ba ṣe abilà ati alami ninu awọn ewurẹ, ti kò si ṣe pupa rúsurusu ninu awọn agutan, on na ni ki a kà si mi li ọrùn bi olè.
34 Labani si wipe, Wò o, jẹ ki o ri bi ọ̀rọ rẹ.
35 Li ọjọ́ na li o si yà awọn obukọ oni-tototó ati alamì, ati gbogbo awọn ewurẹ ti o ṣe abilà ati alamì, ati gbogbo awọn ti o ní funfun diẹ lara, ati gbogbo oni-pupa rúsurusu ninu awọn agutan, o si fi wọn lé awọn ọmọ rẹ̀ lọwọ.
36 O si fi ìrin ọjọ́ mẹta si agbedemeji on tikalarẹ̀ ati Jakobu: Jakobu si mbọ́ agbo-ẹran Labani iyokù.
37 Jakobu si mú ọpá igi-poplari tutù, ati igi haseli, ati kesnuti; o si bó wọn li abófin, o si mu ki funfun ti o wà lara awọn ọpá na hàn.
38 O si fi ọpá ti o bó lelẹ niwaju awọn agbo-ẹran li oju àgbará, ni ibi ọkọ̀ imumi, nigbati awọn agbo-ẹran wá mu omi, ki nwọn ki o le yún nigbati nwọn ba wá mumi.
39 Awọn agbo-ẹran si yún niwaju ọpá wọnni, nwọn si bí ẹran oni-tototó, ati abilà, ati alamì.
40 Jakobu si yà awọn ọdọ-agutan, o si kọju awọn agbo-ẹran si oni-tototó, ati gbogbo onìpupa rúsurusu ninu agbo-ẹran Labani: o si fi awọn agbo-ẹran si ọ̀tọ fun ara rẹ̀, kò si fi wọn sinu ẹran Labani.
41 O si ṣe, nigbati ẹran ti o lera jù ba yún, Jakobu a si fi ọpá na lelẹ niwaju awọn ẹran na li oju àgbará, ki nwọn o le ma yún lãrin ọpá wọnni.
42 Ṣugbọn nigbati awọn ẹran ba ṣe alailera, on ki ifi si i; bẹ̃li ailera ṣe ti Labani, awọn ti o lera jẹ́ ti Jakobu.
43 ọkunrin na si pọ̀ gidigidi, o si li ẹran-ọ̀sin pupọ̀, ati iranṣẹbinrin, ati iranṣẹkunrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ.