Gẹn 14 YCE

Abramu Gba Lọti sílẹ̀

1 O SI ṣe li ọjọ́ Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu, ati Tidali ọba awọn orilẹ-ède;

2 Ti nwọn ba Bera ọba Sodomu jagun, pẹlu Birṣa ọba Gomorra, Ṣinabu ọba Adma, ati Semeberi ọba Seboimu, pẹlu ọba Bela (eyini ni Soari).

3 Gbogbo awọn wọnyi li o dapọ̀ li afonifoji Siddimu, ti iṣe Okun Iyọ̀.

4 Nwọn sìn Kedorlaomeri li ọdún mejila, li ọdún kẹtala nwọn ṣọ̀tẹ.

5 Li ọdún kẹrinla ni Kedorlaomeri, wá ati awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn kọlu awọn Refaimu ni Aṣteroti-Karnaimu, ati awọn Susimu ni Hamu, ati awọn Emimu ni pẹtẹlẹ Kiriataimu,

6 Ati awọn ara Hori li oke Seiri wọn, titi o fi de igbo Parani, ti o wà niha ijù.

7 Nwọn si pada, nwọn si wá si Enmiṣpati, eyini ni Kadeṣi, nwọn si kọlu gbogbo oko awọn ara Amaleki, ati awọn ara Amori ti o tẹdo ni Hasesontamari pẹlu.

8 Ọba Sodomu si jade, ati ọba Gomorra, ati ọba Adma, ati ọba Seboimu, ati ọba Bela, (eyini ni Soari;) nwọn si tẹgun si ara wọn li afonifoji Siddimu;

9 Si Kedorlaomeri ọba Elamu, ati si Tidali ọba awọn orilẹ-ède, ati Amrafeli ọba Ṣinari, ati Arioku ọba Ellasari, ọba mẹrin si marun.

10 Afonifoji Siddimu si jẹ kìki kòto ọ̀da-ilẹ; awọn ọba Sodomu ati ti Gomorra sá, nwọn si ṣubu nibẹ̀; awọn ti o si kù sálọ si ori oke.

11 Nwọn si kó gbogbo ẹrù Sodomu on Gomorra ati gbogbo onjẹ wọn, nwọn si ba ti wọn lọ.

12 Nwọn si mu Loti, ọmọ arakunrin Abramu, ti ngbé Sodomu, nwọn si kó ẹrù rẹ̀, nwọn si lọ.

13 Ẹnikan ti o sá asalà de, o si rò fun Abramu Heberu nì; on sa tẹdo ni igbo Mamre ara Amori, arakunrin Eṣkoli ati arakunrin Aneri: awọn wọnyi li o mba Abramu ṣe pọ̀.

14 Nigbati Abramu gbọ́ pe a dì arakunrin on ni igbekun, o kó awọn ọmọ ọdọ rẹ̀ ti a ti kọ́, ti a bí ni ile rẹ̀ jade, ọrindinirinwo enia o din meji, o si lepa wọn de Dani.

15 O si pín ara rẹ̀, on, pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, si wọn li oru, o si kọlù wọn, o si lépa wọn de Hoba, ti o wà li apa òsi Damasku:

16 O si gbà gbogbo ẹrù na pada, o si gbà Loti arakunrin rẹ̀ pada pẹlu, ati ẹrù rẹ̀, ati awọn obinrin pẹlu, ati awọn enia.

Mẹlikisẹdẹki Súre fún Abramu

17 Ọba Sodomu si jade lọ ipade rẹ̀ li àbọ iṣẹgun Kedorlaomeri ati awọn ọba ti o pẹlu rẹ̀, li afonifoji Ṣafe, ti iṣe Afonifoji Ọba.

18 Melkisedeki ọba Salemu si mu onjẹ ati ọti waini jade wá: on a si ma ṣe alufa Ọlọrun Ọga-ogo.

19 O si súre fun u, o si wipe, Ibukun ni fun Abramu, ti Ọlọrun ọga-ogo, ẹniti o ni ọrun on aiye.

20 Olubukun si li Ọlọrun ọga-ogo ti o fi awọn ọta rẹ le ọ lọwọ. On si dá idamẹwa ohun gbogbo fun u.

21 Ọba Sodomu si wi fun Abramu pe, Dá awọn enia fun mi, ki o si mu ẹrù fun ara rẹ.

22 Abramu si wi fun ọba Sodomu pe, Mo ti gbé ọwọ́ mi soke si OLUWA, Ọlọrun ọga-ogo, ti o ni ọrun on aiye,

23 Pe, emi ki yio mu lati fọnran owu titi dé okùn bàta, ati pe, emi kì yio mu ohun kan ti iṣe tirẹ, ki iwọ ki o má ba wipe, Mo sọ Abramu di ọlọrọ̀:

24 Bikoṣe kìki eyiti awọn ọdọmọkunrin ti jẹ, ati ipín ti awọn ọkunrin ti o ba mi lọ; Aneri, Eṣkoli, ati Mamre; jẹ ki nwọn ki o mu ipín ti wọn.