Gẹn 34 YCE

Wọ́n fi Ipá bá Dina Lòpọ̀

1 DINA ọmọbinrin Lea, ti o bí fun Jakobu si jade lọ lati wò awọn ọmọbinrin ilu na.

2 Nigbati Ṣekemu, ọmọ Hamori, ara Hiffi, ọmọ alade ilu na ri i, o mú u, o si wọle tọ̀ ọ, o si bà a jẹ́.

3 Ọkàn rẹ̀ si fà mọ́ Dina, ọmọbinrin Jakobu, o si fẹ́ omidan na, o si sọ̀rọ rere fun omidan na.

4 Ṣekemu si sọ fun Hamori baba rẹ̀ pe, Fẹ́ omidan yi fun mi li aya.

5 Jakobu si gbọ́ pe o ti bà Dina ọmọbinrin on jẹ́; njẹ awọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu awọn ẹran ni pápa: Jakobu si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ titi nwọn fi dé.

6 Hamori, baba Ṣekemu, si jade tọ̀ Jakobu lọ lati bá a sọ̀rọ.

7 Awọn ọmọ Jakobu si ti oko dé nigbati nwọn gbọ́: inu awọn ọkunrin na si bàjẹ́, inu si ru wọn gidigidi, nitori ti o ṣe ohun buburu ni Israeli, niti o bá ọmọbinrin Jakobu dàpọ: ohun ti a ki ba ti ṣe.

8 Hamori si bá wọn sọ̀rọ pe, Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, nfẹ́ ọmọbinrin nyin; emi bẹ̀ nyin, ẹ fi i fun u li aya.

9 Ki ẹnyin ki o si bá wa gbeyawo, ki ẹnyin ki o si fi awọn ọmọbinrin nyin fun wa, ki ẹnyin ki o si ma mú awọn ọmọbinrin wa.

10 Ẹnyin o si ma bá wa gbé: ilẹ yio si wà niwaju nyin, ẹnyin o joko ki ẹ si ma ṣòwo ninu rẹ̀, ki ẹ si ma ní iní ninu rẹ̀.

11 Ṣekemu si wi fun baba omidan na ati fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju nyin, ohun ti ẹnyin o si kà fun mi li emi o fi fun nyin.

12 Ẹ bère ana lọwọ mi ati ẹ̀bun bi o ti wù ki o pọ̀ to, emi o si fi fun nyin gẹgẹ bi ẹnyin o ti kà fun mi: ṣugbọn ẹ fun mi li omidan na li aya.

13 Awọn ọmọ Jakobu si fi ẹ̀tan da Ṣekemu ati Hamori baba rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, nitori ti o bà Dina arabinrin wọn jẹ́:

14 Nwọn si wi fun wọn pe, Awa kò le ṣe nkan yi lati fi arabinrin wa fun ẹni alaikọlà, nitori ohun àbuku ni fun wa;

15 Kiki ninu eyi li awa le jẹ fun nyin: bi ẹnyin o ba wà bi awa, pe ki a kọ olukuluku ọkunrin nyin li ilà.

16 Nigbana li awa o fi awọn ọmọbinrin wa fun nyin, awa o si mú awọn ọmọbinrin nyin sọdọ wa; awa o si ma bá nyin gbé, awa o si di enia kanna.

17 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti wa lati kọlà; njẹ awa o mú ọmọbinrin wa, awa o si ba ti wa lọ.

18 Ọ̀rọ wọn si dún mọ́ Hamori, ati Ṣekemu, ọmọ Hamori.

19 Ọdọmọkunrin na kò si pẹ́ titi lati ṣe nkan na, nitoriti o fẹ́ ọmọbinrin Jakobu; o si li ọlá jù gbogbo ara ile baba rẹ̀ lọ.

20 Ati Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wá si ẹnubode ilu wọn, nwọn si bá awọn ara ilu wọn sọ̀rọ wipe,

21 Awọn ọkunrin wọnyi mbá wa gbé li alafia; nitorina ẹ jẹ ki nwọn ki o ma gbé ilẹ yi, ki nwọn ki o si ma ṣòwo nibẹ̀; kiyesi i, ilẹ sa gbàye tó niwaju wọn; ẹnyin jẹ ki a ma fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, ki awa ki o si ma fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn.

22 Kìki ninu eyi li awọn ọkunrin na o ṣe jẹ fun wa, lati ma bá wa gbé, lati di enia kan, bi gbogbo ọkunrin inu wa ba kọlà, gẹgẹ bi nwọn ti kọlà.

23 Tiwa kọ ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ati gbogbo ohunọ̀sin wọn yio ha ṣe? ki a sa jẹ fun wọn nwọn o si ma ba wa joko,

24 Gbogbo awọn ti njade li ẹnubode ilu wọn si fetisi ti Hamori ati ti Ṣekemu ọmọ rẹ̀; a si kọ gbogbo awọn ọkunrin ni ilà, gbogbo ẹniti o nti ẹnubode wọn jade.

25 O si ṣe ni ọjọ́ kẹta, ti ọgbẹ wọn kan, ni awọn ọmọkunrin Jakobu meji si dide, Simeoni ati Lefi, awọn arakunrin Dina, olukuluku nwọn mú idà rẹ̀, nwọn si fi igboyà wọ̀ ilu na, nwọn si pa gbogbo awọn ọkunrin.

26 Nwọn si fi oju idà pa Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀, nwọn si mú Dina jade kuro ni ile Ṣekemu, nwọn si jade lọ.

27 Awọn ọmọ Jakobu si wọle awọn ti a pa, nwọn si kó ilu na lọ, nitori ti nwọn bà arabinrin wọn jẹ́.

28 Nwọn kó agutan wọn, ati akọmalu wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ohun ti o wà ni ilu na, ati eyiti o wà li oko.

29 Ati ọrọ̀ wọn gbogbo, ati gbogbo ọmọ wọn wẹ́rẹ, ati aya wọn ni nwọn dì ni igbekun, nwọn si kó ohun gbogbo ti o wà ninu ile lọ.

30 Jakobu si wi fun Simeoni on Lefi pe, Ẹnyin mu wahalà bá mi niti ẹnyin mu mi di õrun ninu awọn onilẹ, ninu awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi: bi emi kò si ti pọ̀ ni iye, nwọn o kó ara wọn jọ si mi, nwọn o si pa mi: a o si pa mi run, emi ati ile mi.

31 Nwọn si wipe, Ki on ki o ha ṣe si arabinrin wa bi ẹnipe si panṣaga?