Gẹn 11 YCE

Ilé Ìṣọ́ Babeli

1 GBOGBO aiye si jẹ ède kan, ati ọ̀rọ kan.

2 O si ṣe, bi nwọn ti nrìn lati ìha ìla-õrùn lọ, ti nwọn ri pẹtẹlẹ kan ni ilẹ Ṣinari; nwọn si tẹdo sibẹ̀.

3 Nwọn si wi, ikini si ekeji pe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a mọ briki, ki a si sun wọn jina. Briki ni nwọn ni li okuta, ọ̀da-ilẹ ni nwọn si nfi ṣe ọ̀rọ.

4 Nwọn si wipe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a tẹ̀ ilu kan dó, ki a si mọ ile-iṣọ kan, ori eyiti yio si kàn ọrun; ki a si li orukọ, ki a má ba tuka kiri sori ilẹ gbogbo.

5 OLUWA si sọkalẹ wá iwò ilu ati ile-iṣọ́ na, ti awọn ọmọ enia nkọ́.

6 OLUWA si wipe, Kiye si i, ọkan li awọn enia, ède kan ni gbogbo wọn ni; eyi ni nwọn bẹ̀rẹ si iṣe: njẹ nisisiyi kò sí ohun ti a o le igbà lọwọ wọn ti nwọn ti rò lati ṣe.

7 Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a sọkalẹ lọ, ki a dà wọn li ède rú nibẹ̀, ki nwọn ki o máṣe gbedè ara wọn mọ́.

8 Bẹ̃li OLUWA tú wọn ká lati ibẹ̀ lọ si ori ilẹ gbogbo: nwọn si ṣíwọ ilu ti nwọn ntẹdó.

9 Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Babeli; nitori ibẹ̀ li OLUWA gbe dà ède araiye rú, lati ibẹ̀ lọ OLUWA si tú wọn ká kiri si ori ilẹ gbogbo.

Àwọn Ìran Ṣemu

10 Wọnyi ni iran Ṣemu: Ṣemu jẹ ẹni ọgọrun ọdún, o si bí Arfaksadi li ọdún keji lẹhin kíkun-omi.

11 Ṣemu si wà li ẹ̃dẹgbẹta ọdún, lẹhin igbati o bí Arfaksadi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

12 Arfaksadi si wà li arundilogoji ọdún, o si bí Ṣela:

13 Arfaksadi si wà ni irinwo ọdún o le mẹta, lẹhin igbati o bí Ṣela tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

14 Ṣela si wà ni ọgbọ̀n ọdún, o si bí Eberi:

15 Ṣela si wà ni irinwo ọdún o le mẹta lẹhin ti o bí Eberi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

16 Eberi si wà li ọgbọ̀n ọdún o le mẹrin, o si bí Pelegi:

17 Eberi si wà ni irinwo ọdún o le ọgbọ̀n lẹhin igbati o bí Pelegi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

18 Pelegi si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bì Reu:

19 Pelegi si wà ni igba ọdún o le mẹsan lẹhin igbati o bí Reu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

20 Reu si wà li ọgbọ̀n ọdún o le meji, o si bí Serugu:

21 Reu si wà ni igba ọdún o le meje, lẹhin igbati o bí Serugu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

22 Serugu si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bí Nahori:

23 Serugu si wà ni igba ọdún, lẹhin igba ti o bí Nahori tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

24 Nahori si jẹ ẹni ọdún mọkanlelọgbọ̀n o si bí Tera:

25 Nahori si wà li ọgọfa ọdún o dí ọkan, lẹhin igbati o bí Tera tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

26 Tera si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Abramu, Nahori, ati Harani.

Àwọn Ìran Tẹra

27 Iran Tera si li eyi: Tera bi Abramu, Nahori, ati Harani; Harani si bí Loti.

28 Harani si kú ṣaju Tera baba rẹ̀, ni ilẹ ibi rẹ̀, ni Uri ti Kaldea.

29 Ati Abramu ati Nahor si fẹ aya fun ara wọn: orukọ aya Abramu ni Sarai; ati orukọ aya Nahori ni Milka, ọmọbinrin Harani, baba Milka, ati baba Iska.

30 Ṣugbọn Sarai yàgan; kò li ọmọ.

31 Tera si mu Abramu ọmọ rẹ̀, ati Loti, ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ati Sarai aya ọmọ rẹ̀, aya Abramu ọmọ rẹ̀; nwọn si ba wọn jade kuro ni Uri ti Kaldea, lati lọ si ilẹ Kenaani; nwọn si wá titi de Harani, nwọn si joko sibẹ̀.

32 Ọjọ́ Tera si jẹ igba ọdún o le marun: Tera si kú ni Harani.