Gẹn 33 YCE

Jakọbu Pàdé Esau

1 JAKOBU si gbé oju rẹ̀ soke, o si wò, si kiyesi i, Esau dé, ati irinwo ọkunrin pẹlu rẹ̀. On si pín awọn ọmọ fun Lea, ati fun Rakeli, ati fun awọn iranṣẹbinrin mejeji.

2 O si tì awọn iranṣẹbinrin ati awọn ọmọ wọn ṣaju, ati Lea ati awọn ọmọ rẹ̀ tẹle wọn, ati Rakeli ati Josefu kẹhin.

3 On si kọja lọ siwaju wọn, o si wolẹ li ẹrinmeje titi o fi dé ọdọ arakunrin rẹ̀.

4 Esau si sure lati pade rẹ̀, o si gbá a mú, o si rọmọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: nwọn si sọkun.

5 O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri awọn obinrin ati awọn ọmọ; o si bi i pe, Tani wọnyi pẹlu rẹ? On si wipe, Awọn ọmọ ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ fun iranṣẹ rẹ ni.

6 Nigbana li awọn iranṣẹbinrin sunmọ ọdọ rẹ̀, awọn ati awọn ọmọ wọn, nwọn si tẹriba.

7 Ati Lea pẹlu ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba: nikẹhin ni Josefu ati Rakeli si sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba.

8 O si wipe, Kini iwọ fi ọwọ́ ti mo pade ni pè? On si wipe, Lati fi ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi ni.

9 Esau si wipe, Emi ní tó, arakunrin mi; pa eyiti o ní mọ́ fun ara rẹ.

10 Jakobu si wipe, Bẹ̃kọ, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi, njẹ gbà ọrẹ mi lọwọ mi: nitori ti emi sa ri oju rẹ bi ẹnipe emi ri oju Ọlọrun, ti inu rẹ si dùn si mi;

11 Emi bẹ̀ ọ, gbà ẹ̀bun mi ti a mú fun ọ wá; nitori ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ ba mi ṣe, ati pe, nitori ti mo ní tó. O si rọ̀ ọ, on si gbà a.

12 O si wipe, Jẹ ki a bọ́ si ọ̀na ìrin wa, ki a si ma lọ, emi o si ṣaju rẹ.

13 Ṣugbọn on wi fun u pe, oluwa mi mọ̀ pe awọn ọmọ kò lera, ati awọn agbo-ẹran, ati ọwọ́-malu ati awọn ọmọ wọn wà pẹlu mi: bi enia ba si dà wọn li àdaju li ọjọ́ kan, gbogbo agbo ni yio kú.

14 Emi bẹ̀ ọ, ki oluwa mi ki o ma kọja nṣó niwaju iranṣẹ rẹ̀: emi o si ma fà wá pẹlẹ, gẹgẹ bi awọn ẹran ti o saju mi, ati bi ara awọn ọmọ ti le gbà, titi emi o fi dé ọdọ oluwa mi ni Seiri.

15 Esau si wipe, Njẹ ki emi ki o fi enia diẹ silẹ pẹlu rẹ ninu awọn enia ti o pẹlu mi. On si wipe, Nibo li eyini jasi, ki emi ki o sa ri õre-ọfẹ li oju oluwa mi.

16 Esau si pada li ọjọ́ na li ọ̀na rẹ̀ lọ si Seiri.

17 Jakobu si rìn lọ si Sukkotu, o si kọ́ ile fun ara rẹ̀, o si pa agọ́ fun awọn ẹran rẹ̀: nitorina li a ṣe sọ orukọ ibẹ̀ na ni Sukkotu.

18 Jakobu si wá li alafia, si ilu Ṣekemu ti o wà ni ilẹ Kenaani, nigbati o ti Padan-aramu dé: o si pa agọ́ rẹ̀ niwaju ilu na.

19 O si rà oko biri kan, nibiti o gbé ti pa agọ́ rẹ̀ lọwọ awọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu, li ọgọrun owo fadaka.

20 O si tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ̀, o si sọ orukọ rẹ̀ ni El-Elohe-Israeli.