Gẹn 46 YCE

Jakọbu ati Ìdílé Rẹ̀ Lọ sí Ijipti

1 ISRAELI si mú ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n ti on ti ohun gbogbo ti o ní, o si dé Beer-ṣeba, o si rú ẹbọ si Ọlọrun Isaaki baba rẹ̀.

2 Ọlọrun si bá Israeli sọ̀rọ li ojuran li oru, o si wipe, Jakobu, Jakobu. O si wipe, Emi niyi.

3 O si wipe, Emi li Ọlọrun, Ọlọrun baba rẹ: má bẹ̀ru lati sọkalẹ lọ si ilẹ Egipti; nitori ibẹ̀ li emi o gbé sọ iwọ di orilẹ-ède nla.

4 Emi o si bá ọ sọkalẹ lọ si Egipti; emi o si mú ọ goke wá nitõtọ: Josefu ni yio si fi ọwọ́ rẹ̀ pa ọ li oju dé.

5 Jakobu si dide lati Beer-ṣeba lọ: awọn ọmọ Israeli si mú Jakobu baba wọn lọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wọn, ati awọn aya wọn, ninu kẹkẹ́-ẹrù ti Farao rán lati mú u lọ.

6 Nwọn si mú ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ti nwọn ní ni ilẹ Kenaani, nwọn si wá si Egipti, Jakobu, ati gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀:

7 Awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin awọn ọmọ rẹ̀, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ li o mú pẹlu rẹ̀ wá si ilẹ Egipti.

8 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti, Jakobu ati awọn ọmọ rẹ̀: Reubeni, akọ́bi Jakobu.

9 Ati awọn ọmọ Reubeni; Hanoku, ati Pallu, ati Hesroni, ati Karmi.

10 Ati awọn ọmọ Simeoni; Jemueli, ati Jamini, ati Ohadi, ati Jakini, ati Sohari, ati Ṣaulu, ọmọ obinrin ara Kenaani kan.

11 Ati awọn ọmọ Lefi; Gerṣoni, Kohati, ati Merari.

12 Ati awọn ọmọ Judah; Eri ati Onani, ati Ṣela, ati Peresi, ati Sera: ṣugbọn Eri on Onani ti kú ni ilẹ Kenaani. Ati awọn ọmọ Peresi ni Hesroni on Hamulu.

13 Ati awọn ọmọ Issakari; Tola, ati Pufa, ati Jobu, ati Simroni.

14 Ati awọn ọmọ Sebuluni; Seredi, ati Eloni, ati Jaleeli.

15 Awọn wọnyi li awọn ọmọ Lea, ti o bí fun Jakobu ni Padan-aramu, pẹlu Dina ọmọbinrin rẹ̀: gbogbo ọkàn awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, o jẹ́ mẹtalelọgbọ̀n.

16 Ati awọn ọmọ Gadi; Sifioni, ati Haggi, Ṣuni, ati Esboni, Eri, ati Arodi, ati Areli.

17 Ati awọn ọmọ Aṣeri; Jimna, ati Iṣua, ati Isui, ati Beria, ati Sera arabinrin wọn: ati awọn ọmọ Beria; Heberi, ati Malkieli.

18 Wọnyi li awọn ọmọ Silpa, ti Labani fi fun Lea ọmọbinrin rẹ̀, wọnyi li o si bí fun Jakobu, ọkàn mẹrindilogun.

19 Awọn ọmọ Rakeli aya Jakobu; Josefu ati Benjamini.

20 Manasse ati Efraimu li a si bí fun Josefu ni ilẹ Egipti, ti Asenati ọmọbinrin Potifera alufa Oni bí fun u.

21 Ati awọn ọmọ Benjamini; Bela, ati Bekeri, ati Aṣbeli, Gera, ati Naamani, Ehi, ati Roṣi, Muppimu, ati Huppimu, ati Ardi.

22 Wọnyi li awọn ọmọ Rakeli, ti a bí fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ mẹrinla.

23 Ati awọn ọmọ Dani; Huṣimu.

24 Ati awọn ọmọ Naftali; Jahseeli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣillemu.

25 Wọnyi si li awọn ọmọ Bilha, ti Labani fi fun Rakeli ọmọbinrin rẹ̀, o si bí wọnyi fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ meje.

26 Gbogbo ọkàn ti o ba Jakobu wá si Egipti, ti o si ti inu Jakobu jade, li àika aya awọn ọmọ Jakobu, ọkàn na gbogbo jẹ́ mẹrindilãdọrin;

27 Ati awọn ọmọ Josefu ti a bí fun u ni Egipti jẹ́ ọkàn meji; gbogbo ọkàn ile Jakobu, ti o wá si ilẹ Egipti jẹ́ ãdọrin ọkàn.

Jakọbu ati Ìdílé Rẹ̀ ní Ijipti

28 O si rán Judah siwaju rẹ̀ si Josefu ki o kọju wọn si Goṣeni; nwọn si dé ilẹ Goṣeni.

29 Josefu si dì kẹkẹ́ rẹ̀, o si lọ si Goṣeni lọ ipade Israeli baba rẹ̀, o si fi ara rẹ̀ hàn a; on si rọ̀ mọ́ ọ li ọrùn, o si sọkun si i li ọrùn pẹ titi.

30 Israeli si wi fun Josefu pe, Jẹ ki emi ki o kú wayi, bi mo ti ri oju rẹ yi, nitori ti iwọ wà lãye sibẹ̀.

31 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀, ati fun awọn ara ile baba rẹ̀ pe, Emi o goke lọ, emi o si sọ fun Farao, emi o si wi fun u pe, Awọn arakunrin mi, ati awọn ara ile baba mi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, nwọn tọ̀ mi wá;

32 Oluṣọ-agutan si li awọn ọkunrin na, ẹran sisìn ni iṣẹ wọn; nwọn si dà agbo-ẹran ati ọwọ́-ẹran wọn wá, ati ohun gbogbo ti nwọn ní.

33 Yio si ṣe, nigbati Farao ba pè nyin, ti yio si bi nyin pe, Kini iṣẹ nyin?

34 Ki ẹnyin ki o wipe, Òwo awọn iranṣẹ rẹ li ẹran sisìn lati ìgba ewe wa wá titi o fi di isisiyi, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu: ki ẹnyin ki o le joko ni ilẹ Goṣeni; nitori irira li oluṣọ-agutan gbogbo si awọn ara Egipti.