10 Ìyan kan si mu ni ilẹ na: Abramu si sọkalẹ lọ si Egipti lati ṣe atipo nibẹ̀; nitoriti ìyan na mu gidigidi ni ilẹ na.
11 O si ṣe, nigbati o kù si dẹ̀dẹ lati wọ̀ Egipti, o wi fun Sarai aya rẹ̀ pe, Kiyesi i nisisiyi, emi mọ̀ pe arẹwà obinrin lati wò ni iwọ:
12 Nitorina yio si ṣe, nigbati awọn ara Egipti yio ri ọ, nwọn o wipe, aya rẹ̀ li eyi: nwọn o si pa mi, ṣugbọn nwọn o dá ọ si.
13 Mo bẹ̀ ọ, wipe, arabinrin mi ni iwọ iṣe: ki o le irọ̀ mi lọrùn nitori rẹ; ọkàn mi yio si yè nitori rẹ.
14 O si ṣe nigbati Abramu de Egipti, awọn ara Egipti wò obinrin na pe arẹwà enia gidigidi ni.
15 Awọn ijoye Farao pẹlu ri i, nwọn si ròhin rẹ̀ niwaju Farao; a si mu obinrin na lọ si ile Farao.
16 O si nṣikẹ Abramu gidigidi nitori rẹ̀: on si li agutan, ati akọ-malu, ati akọ-kẹtẹkẹtẹ, ati iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, abo-kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ.