14 OLUWA si wi fun Abramu, lẹhin igbati Loti yà kuro lọdọ rẹ̀ tan pe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò lati ibi ti o gbé wà nì lọ, si ìha ariwa, ati si ìha gusu, si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ìwọ-õrùn:
15 Gbogbo ilẹ ti o ri nì, iwọ li emi o sa fi fun ati fun irú-ọmọ rẹ lailai.
16 Emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi erupẹ ilẹ: tobẹ̃ bi o ba ṣepe enia kan ba le kà iye erupẹ ilẹ, on li a o to le kaye irú-ọmọ rẹ pẹlu.
17 Dide, rìn ilẹ na já ni ìna rẹ̀, ati ni ibú rẹ̀; nitori iwọ li emi o fi fun.
18 Nigbana ni Abramu ṣí agọ́ rẹ̀, o si wá o si joko ni igbo Mamre, ti o wà ni Hebroni, o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA.