1 O SI ṣe li ọjọ́ Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu, ati Tidali ọba awọn orilẹ-ède;
2 Ti nwọn ba Bera ọba Sodomu jagun, pẹlu Birṣa ọba Gomorra, Ṣinabu ọba Adma, ati Semeberi ọba Seboimu, pẹlu ọba Bela (eyini ni Soari).
3 Gbogbo awọn wọnyi li o dapọ̀ li afonifoji Siddimu, ti iṣe Okun Iyọ̀.
4 Nwọn sìn Kedorlaomeri li ọdún mejila, li ọdún kẹtala nwọn ṣọ̀tẹ.
5 Li ọdún kẹrinla ni Kedorlaomeri, wá ati awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn kọlu awọn Refaimu ni Aṣteroti-Karnaimu, ati awọn Susimu ni Hamu, ati awọn Emimu ni pẹtẹlẹ Kiriataimu,
6 Ati awọn ara Hori li oke Seiri wọn, titi o fi de igbo Parani, ti o wà niha ijù.