17 O si ṣe nigbati nwọn mu wọn jade sẹhin odi tan, li o wipe, Sá asalà fun ẹmi rẹ; máṣe wò ẹhin rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe duro ni gbogbo pẹtẹlẹ; sá asalà lọ si ori oke, ki iwọ ki o má ba ṣegbe.
18 Loti si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi:
19 Kiyesi i na, ọmọ-ọdọ rẹ ti ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, iwọ si ti gbe ãnu rẹ ga, ti iwọ ti fi hàn mi ni gbigbà ẹmi mi là; ṣugbọn emi ki yio le salọ si ori oke, ki ibi ki o má ba bá mi nibẹ̀, ki emi ki o má ba kú.
20 Kiyesi i na, ilu yi sunmọ tosi lati sá si, kekere si ni: jọ̃, jẹ ki nsalà si ibẹ, (kekere ha kọ?) ọkàn mi yio si yè.
21 O si wi fun u pe, Wò o, mo gbà fun ọ niti ohun kan yi pẹlu pe, emi ki yio run ilu yi, nitori eyiti iwọ ti sọ.
22 Yara, salà sibẹ̀; nitori emi kò le ṣe ohun kan titi iwọ o fi de ibẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Soari.
23 Orùn là sori ilẹ nigbati Loti wọ̀ ilu Soari.