14 Abimeleki si mu agutan, ati akọmalu, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, o si fi wọn fun Abrahamu, o si mu Sara, aya rẹ̀, pada fun u.
15 Abimeleki si wipe, Kiyesi i, ilẹ mi niyi niwaju rẹ: joko nibiti o wù ọ.
16 O si wi fun Sara pe, Kiyesi i, mo fi ẹgbẹrun ìwọn fadaka fun arakunrin rẹ: kiyesi i, on ni ibojú fun ọ fun gbogbo awọn ti o wà lọdọ rẹ, ati niwaju gbogbo awọn ẹlomiran li a da ọ lare.
17 Abrahamu si gbadura si Ọlọrun: Ọlọrun si mu Abimeleki li ara dá, ati aya rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin-ọdọ rẹ̀; nwọn si bimọ.
18 Nitori OLUWA ti sé inu awọn ara ile Abimeleki pinpin, nitori ti Sara, aya Abrahamu.