7 Njẹ nitori na mu aya ọkunrin na pada fun u; woli li on sa iṣe, on o si gbadura fun ọ, iwọ o si yè: bi iwọ kò ba si mu u pada, ki iwọ ki o mọ̀ pe, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo ẹniti o jẹ tirẹ.
8 Nitorina Abimeleki dide ni kutukutu owurọ̀, o si pè gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si wi gbogbo nkan wọnyi li eti wọn: ẹ̀ru si bà awọn enia na gidigidi.
9 Nigbana li Abimeleki pè Abrahamu, o si wi fun u pe, Kili o ṣe si wa yi? ẹ̀ṣẹ kini mo ṣẹ̀ ọ, ti iwọ fi mu ẹ̀ṣẹ nla wá si ori mi, ati si ori ijọba mi? iwọ hùwa si mi ti a ki ba hù.
10 Abimeleki si wi fun Abrahamu pe, Kini iwọ ri, ti iwọ fi ṣe nkan yi?
11 Abrahamu si wipe, Nitoriti mo rò pe, nitõtọ ẹ̀ru Ọlọrun kò sí nihinyi; nwọn o si pa mi nitori aya mi.
12 Ati pẹlupẹlu nitõtọ arabinrin mi ni iṣe, ọmọbinrin baba mi ni, ṣugbọn ki iṣe ọmọbinrin iya mi; o si di aya mi.
13 O si ṣe nigbati Ọlọrun mu mi rìn kiri lati ile baba mi wá, on ni mo wi fun u pe, eyi ni ore rẹ ti iwọ o ma ṣe fun mi; nibikibi ti awa o gbé de, ma wi nipa ti emi pe, arakunrin mi li on.