1 SARA si di ẹni ẹtadilãdoje ọdún: iye ọdún aiye Sara li eyi.
2 Sara si kú ni Kirjat-arba; eyi na ni Hebroni ni ilẹ Kenaani: Abrahamu si wá lati ṣọ̀fọ Sara ati lati sọkun rẹ̀.
3 Abrahamu si dide kuro niwaju okú rẹ̀, o si sọ fun awọn ọmọ Heti, wipe,
4 Alejò ati atipo li emi iṣe lọdọ nyin: ẹ fun mi ni ilẹ-isinku lãrin nyin, ki emi ki o le sin okú mi kuro ni iwaju mi.
5 Awọn ọmọ Heti si dá Abrahamu lohùn, nwọn si wi fun u pe,
6 Oluwa mi, gbọ́ ti wa: alagbara ọmọ-alade ni iwọ lãrin wa: ninu ãyò bojì wa ni ki o sin okú rẹ; kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio fi ibojì rẹ̀ dù ọ, ki iwọ ki o má sin okú rẹ.
7 Abrahamu si dide duro, o si tẹriba fun awọn enia ilẹ na, fun awọn ọmọ Heti.