7 Awọn ọkunrin ibẹ̀ na bi i lẽre niti aya rẹ̀: o si wipe, Arabinrin mi ni: nitoriti o bẹ̀ru ati wipe, Aya mi ni; o ni, ki awọn ọkunrin ibẹ̀ na ki o má ba pa mi nitori Rebeka; nitoriti on li ẹwà lati wò.
8 O si ṣe nigbati o joko nibẹ̀ pẹ titi, ni Abimeleki, ọba awọn ara Filistia, wò ode li ojuferese, o si ri, si kiyesi i, Isaaki mba Rebeka aya rẹ̀ wẹ́.
9 Abimeleki si pè Isaaki, o si wipe, Kiyesi i, nitõtọ aya rẹ ni iṣe: iwọ ha ti ṣe wipe, Arabinrin mi ni? Isaaki si wi fun u pe, Nitoriti mo wipe, ki emi ki o má ba kú nitori rẹ̀.
10 Abimeleki si wipe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? Bí ọkan ninu awọn enia bá lọ bá aya rẹ ṣe iṣekuṣe nkọ? iwọ iba si mu ẹ̀ṣẹ wá si ori wa.
11 Abimeleki si kìlọ fun gbogbo awọn enia rẹ̀ wipe, Ẹnikẹni ti o ba tọ́ ọkunrin yi tabi aya rẹ̀, kikú ni yio kú.
12 Nigbana ni Isaaki funrugbìn ni ilẹ na, o si ri ọrọrún mu li ọdún na; OLUWA si busi i fun u:
13 Ọkunrin na si di pupọ̀, o si nlọ si iwaju, o si npọ̀ si i titi o fi di enia nla gidigidi.