13 Iya rẹ̀ si wi fun u pe, lori mi ni ki egún rẹ wà, ọmọ mi: sá gbọ́ ohùn mi, ki o si lọ mu wọn fun mi wá.
14 O si lọ, o mu wọn, o si fà wọn tọ̀ iya rẹ̀ wá: iya rẹ̀ si sè ẹran adidùn; bi irú eyiti baba rẹ̀ fẹ́.
15 Rebeka si mu ãyo aṣọ Esau, ọmọ rẹ̀ ẹgbọ́n, ti o wà lọdọ rẹ̀ ni ile, o si fi wọn wọ̀ Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo:
16 O si fi awọ awọn ọmọ ewurẹ wọnni bò o li ọwọ́, ati si ọbọrọ́ ọrùn rẹ̀:
17 O si fi ẹran adidùn na, ati àkara ti o ti pèse, le Jakobu, ọmọ rẹ̀, lọwọ.
18 O si tọ̀ baba rẹ̀ wá, o wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi; iwọ tani nì ọmọ mi?
19 Jakobu si wi fun baba rẹ̀ pe, Emi Esau akọ́bi rẹ ni; emi ti ṣe gẹgẹ bi o ti sọ fun mi, dide joko, emi bẹ̀ ọ, ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ mi, ki ọkàn rẹ le súre fun mi.