31 On pẹlu si ti sè ẹran adidùn, o si mu u tọ̀ baba rẹ̀ wá, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Ki baba mi ki o dide ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ rẹ̀, ki ọkàn rẹ le sure fun mi.
32 Isaaki baba rẹ̀ si bi i pe, Iwọ tani nì? on si wipe, Emi Esau, ọmọ rẹ akọbi ni.
33 Isaaki si warìri gidigidi rekọja, o si wipe, Tani nla? tali ẹniti o ti pa ẹran-igbẹ́, ti o si gbé e tọ̀ mi wá, emi si ti jẹ ninu gbogbo rẹ̀, ki iwọ ki o to de, emi si ti sure fun u? nitõtọ a o si bukún fun u.
34 Nigbati Esau gbọ́ ọ̀rọ baba rẹ̀, o fi igbe nlanla ta, o si sun ẹkun kikorò gidigidi, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Sure fun mi, ani fun emi pẹlu, baba mi.
35 O si wipe, Arakunrin rẹ fi erú wá, o si ti gbà ibukún rẹ lọ.
36 O si wipe, A kò ha pè orukọ rẹ̀ ni Jakobu ndan? nitori o jì mi li ẹsẹ̀ ni ìgba meji yi: o gbà ogún-ibi lọwọ mi; si kiyesi i, nisisiyi o si gbà ire mi lọ. O si wipe, Iwọ kò ha pa ire kan mọ́ fun mi?
37 Isaaki si dahùn o si wi fun Esau pe, Wõ, emi ti fi on ṣe oluwa rẹ, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li emi ti fi ṣe iranṣẹ rẹ̀; ati ọkà ati ọti-waini ni mo fi gbè e: ewo li emi o ha ṣe fun ọ nisisiyi, ọmọ mi?