6 Rebeka si wi fun Jakobu ọmọ rẹ̀ pe, Wò o, mo gbọ́ baba rẹ wi fun Esau arakunrin rẹ pe,
7 Mu ẹran-igbẹ́ fun mi wá, ki o si sè ẹran adidùn fun mi, ki emi ki o jẹ, ki emi ki o sure fun ọ niwaju OLUWA ṣaju ikú mi.
8 Njẹ nisisiyi, ọmọ mi, gbọ́ ohùn mi, gẹgẹ bi emi o ti paṣẹ fun ọ.
9 Lọ nisisiyi sinu agbo-ẹran, ki o si mu ọmọ ewurẹ meji daradara fun mi lati ibẹ̀ wá: emi o si sè wọn li ẹran adidùn fun baba rẹ, bi irú eyiti o fẹ́:
10 Iwọ o si gbé e tọ̀ baba rẹ lọ, ki o le jẹ, ki o le súre fun ọ, ki on to kú.
11 Jakobu si wi fun Rebeka iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, enia onirun ni Esau arakunrin mi, alara ọbọrọ́ si li emi:
12 Bọya baba mi yio fọwọbà mi, emi o si dabi ẹlẹ̀tan fun u; emi o si mu egún wá si ori mi ki yio ṣe ibukún.